Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Deji ilu Akure ti wọn rọ loye nigba kan, Ọba Adeṣina Oluwadare Adepọju ti waja.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti Ọgbẹni Dapọ Adepọju to jẹ agbẹnusọ fun idile Adesina fi sita, o ṣalaye pe Deji ti wọn rọ loye ọhun ku si ile-iwosan aladaani kan niluu Abuja laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lẹyin aisan ranpẹ to ṣe e.
Adepọju ni tayọtayọ ni Adesina fi gbadura fun alaafia, iṣọkan ati idagbasoke ilu Akurẹ ko too pa oju de.
O ni Deji ana ọhun tun gbadura, o si ṣeleri pe ko ni i pẹ, bẹẹ ni ko ni i jinna rara, ti ọmọ bibi ilu Akurẹ yoo fi di aarẹ orilẹ-ede Naijiria.
Ọba Oluwadare Adepọju Adesina ni Deji karundinlaaadọta ti yoo gori apere awọn baba nla rẹ gẹgẹ bii Deji tilu Akurẹ. Idile ọba Oṣupa lo gori itẹ lẹyin bii ọgọrun-un ọdun ti idile ọba ojijigogun ti jọba kẹyin.
Ọjọ kẹwaa, oṣu kẹfa, ọdun 2010, nijọba Gomina Olusẹgun Mimiko kede yiyọ Ọba Adesina kuro nipo Deji, ti wọn si tun fofin de e pe eegun rẹ ko gbọdọ ṣẹ laarin igboro Akurẹ fun odidi oṣu mẹfa gbako.
Ẹsun ti wọn fi kan an lọdun naa lọhun-un ni pe o lọ si Ojule kọkanlelogoje, Hospital Road, l’Akurẹ, lati kan ọkan ninu awọn olori rẹ, Bolanle Adesina, labuku nita gbangba. Eeru gbigbona ti wọn ti rẹ ni wọn lo da lu obinrin naa, ti ọwọ rẹ si bẹrẹ si i jẹra. Rabaraba iṣẹlẹ naa lo pa olori yii.
Gbogbo akitiyan Ọba ana ọhun lati pada sori apere ọba lo ja si pabo pẹlu bi ile-ẹjọ ṣe kọ lati da a lare lori gbogbo ẹjọ to pe tako iyọnipo rẹ.
Iyalẹnu lo jẹ fawọn araalu nigba ti wọn ri Ọba Adesina to wọlu wẹrẹ ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin toun atawọn alatilẹyin rẹ si n jo kaakiri Akurẹ, ṣugbọn wọn ko ti i rin jinna tawọn agbofinro fi gbe e sinu ọkọ, ti wọn si wa a lọ siluu Ọrẹ pẹlu ikilọ pe ko tun gbọdọ dan iru rẹ wo mọ laye.
Lara awọn aṣeyọri rẹ gẹgẹ bii Deji ni siṣeto awọn ọlọdẹ ibilẹ fun aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilu Akurẹ ati agbegbe rẹ. Ṣiṣe amojuto eto kara-kata laarin ọja, to si ri i daju pe awọn ọlọja ko gbowo lori ọja wọn ju bo ti yẹ lọ.