Ọba tuntun jẹ ni Lafiagi 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni igbimọ afọbajẹ niluu Lafiagi kede Muhammed Kawu, gẹgẹ bii Ẹmir tuntun fun ilu ọhun, lẹyin ti Alaaji Saadu Kewu jade laye.

Ijọba  ipinlẹ Kwara, latọwọ Kọmisanna to n ri sọrọ ijọba ibilẹ ati lọba lọba, Aliyu Saifudeen, si ti buwọ lu iyansipo rẹ gẹgẹ bii Ẹmir Lafiagi tuntun.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni Ẹmir ilu ọhun, Saadu Kewu, dagbere faye ni Abuja lẹyin aisan ranpẹ, ti gbogbo awọn to lero pe awọn lẹtọọ si ipo naa si ti n lọbi lọ koko, ṣugbọn ni bayii wọn ti kede Muhammed Kawu gẹgẹ bii Ẹmir Lafiagi tuntun.

Leave a Reply