Monisọla Saka
Olori orilẹ-ede wa nigba kan, Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti ṣekilọ fun ijọba Naijiria pe ti wọn ko ba wa ọna abayọ si ọrọ awọn ọmọ bii ogun miliọnu ti wọn n fẹsẹ gbalẹ kiri latari airi ileewe lọ, a jẹ pe Naijiria ti tun n pese awọn Boko Haram ọjọ ọla kalẹ niyẹn.
Lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lo sọrọ yii nibi ipade apero ti wọn ṣe lori eto ẹkọ (National Summit on Education Reform 2022) niluu Abuja, eleyii ti ileeṣẹ Olori ilegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, ṣagbekalẹ rẹ. Ọbasanjọ la a mọlẹ pe, nnkan ti agbara orilẹ-ede wa o le ka ni wọn n dagba le, eyi gan-an si ni orisun gbogbo iṣoro ti a n la kọja.
O ni, “Njẹ a rẹni to n ṣakiyesi ọna ti a fi n pọ si i nilẹ yii, ẹ jẹ ka a wo o, lọdun marun-un tabi mẹwaa si isinyii, ṣe nnkan ta a le ṣe si i wa, ti ọrọ naa ko fi ni i buru ju bayii lọ? Yatọ si ounjẹ to jẹ koko, ti a o tilẹ reeyan ronu lori bi iyẹn ko ṣe ni i di iṣoro nla, nitori lẹyin ounjẹ ati ilera, ẹkọ lo tun kan o”.
O ni ki orilẹ-ede yii ronu nipa bi a ṣe n pọ si i lojoojumọ, ki wọn si gbe igbesẹ lori bi iyatọ gidi ṣe maa ba eto ẹkọ.
Nigba to n sọrọ lori ohun to ṣokunfa iṣoro ti Naijiria n dojukọ lọwọ bayii, o ni, “Igba ta a ti ṣina wọgbo lọ ni asiko ti gbogbo agbanla aye ti n jẹran eto ẹkọ ọfẹ lẹnu, ki tolori tẹlẹmu le ni ẹkọ iwe to ye kooro ti awa o si tẹle aba naa la ti ṣina.
Nnkan to ba ni lọkan jẹ ni, bẹẹ lojumọ toni yii, awọn ọmọ bii miliọnu lọna ogun (20 million), to ṣe deede ida mẹwaa gbogbo awa eeyan ta a wa lorilẹ-ede Naijiria, ni wọn ko lanfaani lati kawe. A o si yee ṣina wọgbo latigba naa titi di isinyii, nnkan buruku gbaa si ni. Njẹ ohun kan tilẹ wa ta a le ṣe si i? Mo nigbagbọ pe ọna abayọ wa.
‘‘Ọna abayọ kan ṣoṣo naa si ni pe ka da awọn ọmọ wẹwẹ bii ogun miliọnu yẹn pada sileewe. Ta o ba ti wa ọna bi wọn ṣe maa pada si yara ikẹkọọ, a jẹ pe a ti n palẹ mọ fawọn Boko Haram ọjọ iwaju niyẹn, eyi to n bọ si maa buru ju awọn ta a n ba finra lọwọ bayii lọ. Lojiji bayii lo maa ṣẹlẹ loju gbogbo wa.”
Ninu ọrọ ikini kaabọ rẹ, Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, sọ pe ki Naijiria too le goke agba, wọn gbọdọ pese ayika to rọrun fawọn eeyan ilẹ yii, ki ala igbega tiwọn naa le wa si imuṣẹ, nitori pe irọrun igi naa nirọrun ẹyẹ.