Faith Adebọla
Olori orileede wa, Ajagun-fẹyinti Muhammadu Buhari, ti fẹsun kan Aarẹ tẹlẹ ri, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, o ni oun lo n ṣagbatẹru bawọn kan ṣe fẹẹ gbajọba lọwọ oun, ki wọn si yọ oun nipo.
Ninu atẹjade kan lati ileeṣẹ iroyin rẹ (Buhari Media Organisation) fi lede lọjọ Aiku, Sannde yii, wọn fẹsun kan an pe aarẹ ana kan ti wọn lawọn ko fẹẹ la orukọ rẹ mọlẹ, lo n ṣagbatẹru ipade awọn eeyan pataki pataki kan lawujọ wa, ti wọn si fẹẹ fori kori lori bi wọn ṣe maa le Aarẹ Buhari danu tabi ki wọn ni ko kọwe fipo silẹ lọran-anyan.
Atẹjade ọhun, ti alaga BMO, Niyi Akinsoju ati Cassidy Madueke, buwọ lu, sọ pe olobo to lẹsẹ nilẹ lo ta awọn nipa igbesẹ ọhun, iwadii tawọn si ṣe ti fihan pe awọn onitẹmbẹlẹkun kan ni wọn fẹẹ ditẹ mọ Buhari lati le e kuro lori aleefa.
Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Awọn atanilolobo wa ati iṣẹ iwadii ta a ṣe ti fidi ẹ mulẹ pe Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ ri kan ti pari eto lati da wahala silẹ lorileede yii nipa apero kan to fẹẹ pe awọn eeyan pataki pataki lawujọ wa si laipẹ.
“Loootọ, apero lati jiroro bi nnkan ṣe ri lorileede yii ni wọn lawọn fẹẹ pe, ṣugbọn a ti wadii, a si le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe ohun to wa lọkan wọn ni lati da rugudu silẹ nipa kikede gbedeke fun Buhari lati kọwe fipo silẹ, lẹyin ti wọn ba ti panu-pọ pe ijọba rẹ ko kunju oṣuwọn to, tori awọn agbaagba ilu lawọn kọyin si i.
“Ohun to mu ki ọrọ igbesẹ aarẹ tẹlẹri yii kọọyan lominu ni pe yatọ si ti pe iru apero yii ko bofin mu, ero adaluru to wa lọkan olori orileede ta a n sọrọ rẹ yii gba ifura paapaa ta a ba ranti pe laipẹ yii lawọn alagbara kan doju ijọba demọkiresi de lorileede Iwọ-Oorun Afrika kan. Iru awọn ikorajọ yii le da yanpọnyanrin silẹ.
Tori bẹẹ, a ke si ẹyin ọmọ Naijiria lati lakiyesi pẹlu bawọn eeyan kan ṣe n pa kubẹkubẹ kaakiri lasiko yii, ti wọn si ti pinnu lati yi ọkọ ijọba awa-ara-wa to ṣọwọn bii oju yii, danu soju agbami.”