Jide Kazeem
Awọn olori ilẹ wa tẹlẹ, Olusẹgun Ọbasanjọ ati Yakubu Gowon, Earnest Ṣhonekan ati Abdulsalam Abubakar ti n ṣepade pọ pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lori ẹrọ ayelujara.
Bo tilẹ pe ilu Abuja ni Buhari wa ni tiẹ to ti n ba wọn ṣepade yii, ori ẹrọ ayelujara lawọn olori ile wa telẹ naa ti n ba a sọrọ, nibẹ ni ipade naa ti n lọ lọwọ ba a ṣe n sọ yii.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i le sọ ohun ti ipade naa da le lori, ṣugbọn awọn to mọ bo ṣe n lọ sọ pe ipade naa ko sẹyin rogbodiyan to n lọ nilẹ wa, nibi ti awọn ṣọja ti ṣina ibọn fun awọn ọdọ to n ṣewọde jẹẹjẹ wọn.
A fi ki olorun ko wa yo ninu rogbodiyan to nlo lowo Yi. Adura lole se o.