Ọbasanjọ kọ lẹta si wọn ni London nitori Ekweremadu

Adewale Adeoye

Nitori ọkan ninu awọn aṣofin ilẹ wa, Oloye Ike Ekweremadu, to ha siluu oyinbo lori ẹsun ṣiṣowo ẹya ara eeyan, aarẹ orilẹ-ede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti kọ lẹta pataki kan si awọn alaṣẹ kootu ilẹ okeere, Old Bailey, nibi ti igbakeji olori ileegbimọ aṣofin ilẹ wa tẹlẹ, Oloye Ike Ekweremadu, ti n jẹjọ lori ẹsun iwa ṣiṣowo ẹya ara eeyan ti wọn fi kan an.

Oloye Ike Ekweremadu pẹlu iyawo rẹ, Abilekọ Beatrice Ekweremadu, ni wọn jọ n jẹjọ ẹsun iwa ọdaran pe wọn dọgbon mu ọdọmọdekunrin kan lọ soke okun lati lọọ yọ kidinrin rẹ lati fi rọpo ti ọmọ wọn, Omidan Sonia to n gbe lorilẹ-ede England, to ni aarun kindinrin.

Ninu lẹta Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ọhun, eyi to kọ si akọwe ile-ẹjọ naa ni Ọbasanjọ ti sọ pe ki awọn alaṣẹ ijọba ilẹ naa ṣiju aanu wo Ekweremadu, ki won si fi ohun to ṣe naa fa a leti, nitori ọkunrin naa ti mọ pe ohun ti oun ṣe naa ki i ṣe ohun to dara rara.

O ti le daadaa lọdun kan bayii ti aṣofin ilẹ wa naa, Dokita Obata pẹlu iyawo rẹ, ti n jẹjọ ẹsun iwa ọdaran naa, ṣugbọn laipẹ yii lawọn mejeeji jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Pẹlu ohun Ekweremadu sọ yii, ile-ẹjọ ọhun ti sọ pe ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni wọn yoo ṣe idajọ wọn.

Ọbasanjọ ni, Mo mọ daadaa pe ohun ti won ṣe ko daa, ti ko si yẹ rara ki wọn faaye gba ẹni ti wọn ba mu lori, rẹ paapaa ju lọ nibi ti ọlaju de yii, ṣugbọn nitori ibaṣepọ to daa tẹlẹ to ti wa laarin orilẹ-ede mejeeji, ti o si tun jẹ pe Ekweremadu jẹ ọkan pataki lara awọn sẹnetọ Naijiria, mo n fi akoko yii rawọ ẹbẹ si awọn alaṣẹ kọọtu yii pe ki wọn ṣiju aanu wo aṣofin yii, ki wọn fi eyi fa a leti, paapaa ju lọ ki wọn ro ti ọmọ wọn to nilo itọju gidi gan-an bayii, ki wọn din ijiya rẹ ku.

 

Leave a Reply