Ẹ pada wa sile ki wọn le ka yin ninu eto sẹnsọ to n bo lọna -IPOB

Adewale Adeoye

Ẹgbẹ awọn ọmọ ilẹ Ibo kan ti wọn n pe ni ‘Indigenious People Of Biafra’ (IPOB), ti rọ gbogbo awọn ojulowo ọmọ ilẹ Ibo jake-jade orilẹ-ede yii pe ki gbogbo wọn patapata pada wa sile bi akoko eto ikaniyan ti ijọba apapọ ilẹ wa fẹẹ bẹrẹ laipẹ yii ba to.

Ẹgbẹ IPOB ni o ṣe pataki gan-an fawọn ọmọ bibi ẹya Ibo ti wọn wa kaakiri origun mẹrẹẹrin orilẹ-ede yii lati pada wa sile baba wọn lakooko eto ikaniyan naa, ki wọn le mo iye wọn gan-an, ati lati le sọ fawon agbaye pe wọn ki i ṣe eeyan tabi ẹya ti awọn kan le fọwọ yẹpẹrẹ rẹ rara.

Alukoro agbe ẹgbẹ IPOB naa, Ogbẹni Emma Powerfull, lo sọrọ ọhun di mimọ laipẹ yii. O sọ pe akoko ree fawọn ẹya Ibo lati sọ fagbaaye pe awọn pọ daadaa ju iye ti wọn lero rẹ lọ

O ni, ‘Bi awọn ọmọ ilẹ wa gbogbo ba le dari pada wa sile lakooko eto ikaniyan naa, yoo jẹ anfaani nla gan-an fun wa lati mọ iye ti a jẹ. Awọn kan n ro pe a ko pọ rara to iye to le da duro gẹgẹ bii orilẹ-ede kan.

Eyi si wa lara awọn ohun ti wọn fi maa n tabuku wa nigba gbogbo pe a kere niye, ṣugbọn bi wọn ba le wa sile lakooko naa ki won ka gbogbo wọn pata, o daju pe wọn yoo mọ pe loootọ la pọ daadaa to ẹni to le da duro gẹgẹ bii orilẹ-ede kan.

Ṣugbọn bi e ba ri ohun kan ti ko le jẹ ki ẹ wa sile lakooko naa, ẹ ma ṣe jẹ ki wọn ka yin mọ awọn araalu ibomiiran, a ki i ṣe omugọ rara’.

O ni oun paapaa yoo gbe igbesẹ pataki bayii lati fọwọ-sowọ-pọ pẹlu awon onimọto gbogbo pe ki wọn maa gbe awọn araalu bọ nile bi akoko ba ti to, ẹni to ba fẹẹ pada wa sile le ṣe bẹẹ nitori pe mọto yoo wa fun ẹnikẹni lati wa sile lakooko eto ikaniyan ọhun.

Alukoro ẹgbẹ IPOB naa rọ gbogbo awọn olowo gbogbo ti wọn jẹ ọmọ Ibo pe ki wọn ṣẹranlọwọ ohun gbogbo ti wọn ba le ṣe lakooko yii ki awọn araalu le pada wa sile fun ikaniyan ti yoo bẹrẹ laipẹ yii.

Leave a Reply