Jọkẹ Amọri
Oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ti fagba han awọn oludije ẹlẹgbẹ rẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Atiku Abubakar nipinlẹ Edo. Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP, labẹ isakoso Godwin Obaseki, lo n dari ipinlẹ naa, oludije ẹgbẹ Labour yii lo lo la gbogbo wọn mọlẹ, ibo to si pọ lo ko nipinlẹ naa.
Nigba ti oludari idibo naa nipinlẹ Edo, Ọjọgbọn Nyaudoh Ndaeyo, n kede esi idibo naa, o ni ijọba ibilẹ mejila ni ẹgbẹ oṣelu Labour ti rọwọ mu, nigba ti oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, mu ijọba ibilẹ mẹfa.
Ibo ọọdunrun le mọkanlelọgbọn (331,163), ni wọn di fun Peter Obi nipinlẹ naa, ẹgbẹ APC ni ibo ẹgbẹrun lọna ogoje ati mẹrin le diẹ (144, 471). Ibo mọkandinlaaadọrun o le diẹ (89, 585), ni oludije ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, ni ni tirẹ. Ẹgbẹ (NNPP) ni ibo ẹgbẹrun mẹta din diẹ (2, 773).
Tẹ o ba gbagbe, ipinlẹ yii ni Adams Osihomhole to ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ APC apapọ ti wa.