Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ariwo, ‘emi naa kọ, mi o mọ-ọn-mọ ṣe e, eṣu lo ti mi’ ni Wolii kan, Festus James, fi bọnu lasiko ti wọn ṣafihan rẹ lolu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Akurẹ, lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ṣalaye fawọn oniroyin pe lọjọ kẹtala, osu kọkanla, ọdun 2021, ni Wolii Festus lọọ ba awọn ijọ kan lalejo niluu Agbabu, nijọba ibilẹ Odigbo, to si ni Ọlọrun lo ran oun wa lati Ibadan koun waa ba wọn ṣe isọji ọlọjọ mẹta.
Ọjọ keji ti isọji ọhun bẹrẹ lo riran si ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan to loyun oṣu mẹjọ sinu.
Wolii Festus ni ọmọbinrin naa gbọdọ ri oun lẹyin isin nitori pe oun niṣẹ pataki kan ti ẹmi Ọlọrun ran oun si i.
Obinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri ọhun duro gẹgẹ bii iṣẹ ti wọn jẹ fun un.
Bi Wolii Festus ṣe da awọn eeyan yooku to fẹẹ ri i lohun tan lo mu ọmọ naa wọnu yara igbalejo ti wọn fun un, nibi to ti fipa ba a sun daadaa dipo itusilẹ to ni oun fẹẹ ṣe fun un.
Nigba t’ALAROYE n fọrọ wa ọkunrin to pera ẹ lojiṣẹ Ọlọrun ọhun lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ naa sun, bo tilẹ jẹ pe oun ko fipa mu un gẹgẹ bii ẹsun tawọn ọlọpaa fi kan oun.
O ni oun mọ pe ẹmi eṣu lo wọnu oun nitori pe iṣẹlẹ naa ko tinu oun wa.
Abilekọ Ọdunlami ni ọkunrin naa ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ niwọn igba toun funra rẹ ti jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọ ọlọmọ sun.