Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ọlanṣile Nasirudeen lorukọ obinrin yii, iyawo kẹrin ni lọọdẹ ọkọ ẹ, ṣugbọn obinrin kan tun ṣẹṣẹ loyun fọkọ naa bayii, eyi ti Lanṣile gbọ nipa ẹ, to si tori ẹ gun ọkọ wọn pa n’Ijẹbu -Ode ti wọn n gbe.
Alapata ẹran lọkọ obinrin yii, iṣẹ naa ni Lanṣile funra ẹ n ṣe. Obinrin to fẹẹ diyawo karun-un lọọdẹ ọkọ wọn ni wọn lo wa sódò ẹran laipẹ yii, ni Lanṣile to ti gbọ nipa oyun obinrin naa ba ko o loju.
O ni ẹtọ wo lo ni lati lóyún fọkọ oun, aya ko o to bẹẹ, o tun yọju si odo ẹran toun atọkọ oun wa, lọrọ ba dariwo.
Iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lodo ẹran naa lo tun faja laarin Lanṣile, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta (47), ati ọkọ rẹ to jẹ ẹni ọdun mọkanlelaaadọta (51).
Bi Lanṣile ṣe fa ọbẹ yọ niyẹn, lo ba fi gun ọkọ rẹ lẹsẹ osi, ni iṣan ẹsẹ ba ja.
Wọn sare gbe ọkunrin naa lọ sọsibitu kan fun itọju pajawiri, awọn yẹn pada ni ki wọn maa gbe e lọ sọsibitu Jẹnẹra Ìjẹ̀bú-Ode. Ṣugbọn nibi ti wọn ti n tọju rẹ lọwọ lo ti dagbere faye, wọn ni ẹjẹ to pọ lo ti danu lara rẹ.
Ni wọn ba mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Ìjẹ̀bú-Ode, lawọn ọlọpaa ba lọ sile awọn Lanṣile lati mu un, ṣugbọn o ti sa lọ.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Mobalufọn, n’Ijẹbu –Ode, kan naa ni wọn ti pada ri i mu.
Nigba ti wọn beere idi to fi gun ọkọ ẹ lọbẹ, Lanṣile sọ pe ọkunrin naa lo kọkọ gba oun leti, nitori oun kan beere lọwọ iyawo ẹ tuntun naa pe ki lo waa ṣe nisọ awọn si ni.
Wọn ti sinku ọkunrin naa nilana ẹsin Islam, lẹyin ti wọn ṣayẹwo oyinbo lati mọ ohun to fa iku rẹ gan-an.
Lanṣile naa ti wa lẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaayan, iwadii awọn ọlọpaa si n tẹsiwaju lori rẹ gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣe sọ.