Nitori biliọnu rẹpẹtẹ ti wọn na lori omi ti ko yọ, Abdulrasaq sọko ọrọ si gomina Kwara tẹlẹ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti soko ọrọ si ojúgbà rẹ to ṣejọba tẹlẹ, Fatai Ahmed, lori biliọnu mẹfa to na lori omi nipinlẹ Kwara, sugbọn tawọn ko ri  omi kankan nigboro, to jẹ ninu eto isuna ni awọn ti n ri i.

Abdulrahman sọ eleyii di mimọ ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lasiko to n gbalejo awọn asoju Emir ilu Lafiagi Alhaji Ṣa’adu Kawu Haliru, ti wọn ṣe abẹwo si i ni ilu llọrin. Gomina ni ipo ti awọn ba ọrọ omi nigba tawọn gbakoso ijọba ko dara, o ni gbogbo omi lo dẹnukọlẹ, ti awọn oṣiṣẹ eto omi si wa ni iyansẹlodi nigba naa. O fi kun un pe iṣoro tawọn eeyan n doju kọ nigboro Ilọrin ni pe gbogbo awọn ọpa omi lo ti bẹ tan, ti ko si omi horo kan nigboro. Gomina ni gbogbo awọn faili ti wọn fi gbe iṣẹ ohun jade lo ti poora, to fi mọ orukọ awọn agbaṣẹṣe to gba awọn iṣẹ akanṣe ọhun.

Awọn ti wọn waa ṣe abẹwo ọhun ni Salihu Talban Lafiagi to jẹ agbẹnusọ fun gbogbo awọn to ku rẹ. Lara awọn ti wọn tun jọ kọwọọrin lọ sọdọ gomina ni Ndaji ti ilu Lafiagi, Alhaji Ahmed Yahya Maka a, Sha-aba Lafiagi, Alhaji Abdulrahman Manzuma, Walin Lafiagi, Adajọ Idris Adam ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn waa lu gomina lọgọ ẹnu lori iṣẹ akanṣe to ti ṣe si ilu Lafiagi lẹnu igba perete to gori aleefa. Ninu ọrọ Akọwe iroyin fun gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, to fi iroyin naa lede fawọn oniroyin niluu Ilọrin, o naka abuku si gomina ana, Fatai Ahmed, lori ipo ti wọn fi omi si ko too di pe saa rẹ tẹnu bọpo.

Leave a Reply