Ina gaasi tun jo eeyan meji pa nile Ọbasanjọ, l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Eeyan meji mi-in ni wọn tun ti di oku bayii latari ina gaasi to tun jo wọn pa ninu ọgba Oluṣẹgun Obasanjọ Presidential Library(OOPL), l’Abẹokuta.

Nnkan bii aago mọkanla aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ogunjọ, oṣu karun-un yii, ni awọn ọkunrin meji ti wọn jẹ oniṣẹ-ọwọ, n rọ afẹfẹ gaasi sinu ẹrọ amuletutu kan, eyi to wa ninu ‘Marcque Event Centre’ ninu ọgba naa, bi gaasi ọhun ṣe gbina lojiji niyẹn, to jo wọn pa.

Ẹ oo ranti pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni ina gaasi pa eeyan meji ni Conference Hotel, ti i ṣe ti Ọtunba Gbenga Daniel, l’Abẹokuta kan naa, ti eeyan mẹta mi-in si fara pa, iyẹn lẹyin iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lọsẹ to kọja, ti ina gaasi pa eeyan mẹfa l’Abẹokuta kan naa.

Laarin ọsẹ meji, ko din leeyan meje to ti gbẹmi-in mi bayii l’Abẹokuta, latari gaasi to n bu gbaamu lojiji bi wọn ba ti n fi ṣiṣẹ lọwọ.

Leave a Reply