Ki ẹni ti ofin fifi maaluu jẹko ni gbangba ta a ṣe ko ba tẹ lọrun gba ile-ẹjọ lọ-Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti sọ kobakungbe ọrọ si Minisita feto idajọ lorilẹ-ede yii, Amofin Agba Shehu Malami, fun bo ṣe sọrọ ta ko bawọn gomina ẹkun Guusu ṣe kede fífi ofin de kiko ẹran jẹ nita gbangba.

Ninu atẹjade kan ti Arakunrin funra rẹ buwọ lu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lo ti jẹ ko ye adajọ agba pe iwa omugọ patapata ni bo ṣe n ṣakawe awọn afẹmiṣofo darandaran pẹlu awọn to n ta paati ọkọ ninu ọrọ to sọ ta ko igbesẹ ti awọn gomina ẹkun Guusu gbe.

Iru ọrọ tabi afiwe yii lo ni ko yẹ ko jade lẹnu ẹni to pe ara rẹ ni amofin agba.

Aketi ni bawo leeyan ṣe fẹẹ maa ṣafiwe awọn oniṣowo paati ti wọn n ṣiṣẹ oojọ wọn lai fi tiwọn pa ẹlomiiran lara atawọn Fulani darandaran to n gbẹmi alaiṣẹ, ti wọn si tun n ba iṣẹ oniṣẹ jẹ?

O ni gbogbo awọn gomina to wa ni iha ẹkun Guusu lawọn ti pinnu, bẹẹ lawọn ti ṣetan lati ṣamulo ofin tuntun naa lai si ohunkohun to le di i lọwọ.

O ni adajọ agba yii lẹtọọ ati gba ile-ẹjọ lọ ti igbesẹ ti awọn gbe naa ko ba tẹ ẹ lọrun.

 

Leave a Reply