Ifikun-lukun lọna to daa ju lati yanju awọn ipenija to n ba ilẹ wa finra – Sultan Sokoto

Faith Adebọla

Olori ẹsin Musulumi nilẹ wa ati Sultan tilu Ṣokoto, Mohammad Sa’ad Abubakar, ti fọwọ sọya pe mimi ni ẹpọn agbo n mi, ko ni i ja bọ rara. O ni  awọn ipenija ti Naijiria n koju yii ko le yọri si ogun abẹle rara.

Ọjọbọ, Tọsidee, yii, ni ọba alaye onipo ki-in-ni l’Oke-Ọya ọhun sọrọ yii nibi apero kan ti ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ni Naijiria (Nigeria Inter-Religious Council, NIREC) ṣe niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa.

Sultan ni ko sẹni to ṣetan lati ba ẹnikan jagun lorileede yii, ati pe ifori kori, ifikun lukun loun ṣi mọ gẹgẹ bii ọna to daa ju lọ lati wa iyanju sawọn ipenija oriṣiiriṣii to n ba ilẹ wa finra.

O ni: “Awọn eeyan kan ti n sọrọ pe bo ba le dogun ko dogun, wọn logun maa ṣẹlẹ ni Naijiria, mo beere pe ta lo fẹẹ ba ẹnikan jagun? Ninu gbogbo mọlẹbi kọọkan, bawọn Onigbagbọ ṣe wa lawọn ẹlẹsin Musulumi naa wa, ko si idile ti wọn tọpinpin ẹ delẹ ti ko si awọn ẹya mi-in to yatọ nibẹ, ọpọ idile lawọn ọmọ wọn ṣegbeyawo pẹlu ẹya to yatọ si tawọn obi wọn.

Tori naa, ariwo tawọn kan n pa nipa ogun ati ija ko le ṣẹlẹ. Tẹ ẹ ba si wo o, awọn ti ko fẹ kọrọ yii dija lo pọ ju awọn to n pariwo ogun lọ, ọpọ eeyan daadaa to nifẹẹ alaafia, ti wọn si nifẹẹ ọmọlakeji wọn lo ṣi wa, ohun t’Ọlọrun si fọwọ si niyẹn.

“Ẹ jẹ ka ṣi jọọ wa pọ, ka si jọ jokoo papọ, ka jọ jiroro iṣoro wa. Emi gbagbọ daadaa ninu keeyan yanju iṣoro nitunbi inubu tori ohun ti ẹsin mi fi kọ mi lati maa ṣe nigba gbogbo niyẹn.

Mo gbagbọ pe ọrọ ki i tobi ka f’ọbẹ bu u, bo ti wu kiṣoro kan le to, ta a ba jokoo lati fikun lukun nipa ẹ, o maa yanju, tori ki alaafia le wa lawọn kan fi n jagun, ti a ba si le ri alaafia naa lai jagun, ki la waa fẹ doju ibọn kọ ara wa si.”

Leave a Reply