Faith Adebọla
Kayeefi lọrọ naa n ṣe awọn eeyan, ọpọ lo si n beere pe kin niya arugbo kujọkujọ yii, Mary Adebayọ, tun n wa nidii okoowo egboogi oloro lẹni ọgọrin ọdun, latari bawọn ẹṣọ ajọ NDLEA ṣe mu oun ati ọmọọmọ rẹ kan, Funmilayọ Adebayọ, lọjọ Aiku ọsẹ yii, ti wọn si ba oriṣiiriṣii ẹru ofin lọwọ wọn.
Ọga lẹka iroyin fun ajọ NDLEA (National Drug Law Enforcement Agency) Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede fawọn oniroyin.
O ni olobo kan lo ta awọn agbofinro lori okoowo buruku ti wọn fẹsun kan mama arugbo naa pe o n ṣe, lawọn ba bẹrẹ si i fimu finlẹ, iwadii si fihan pe bi wọn ṣe sọ ọ, bẹẹ lawọn ba a, nigba tawọn lọọ ṣayẹwo ile rẹ to wa l’Opopona Ayeyẹmi, nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, lọjọ Sannde ọhun.
Wọn ni nibi tobinrin naa ti jingiri ninu apade alude tita egboogi oloro de, ki i ṣe igbo nikan lawọn ba nile rẹ, wọn tun ba awọn egboogi ti ko bofin mu bii kokeeni, heroin, methamphetamine, tramadol, swinol ati ọkan ti wọn n pe ni skuchies.
Wọn ni ẹru kokeeni tawọn ka mọ ọn lọwọ, nigba ti wọn ko o sori iwọn, o ku diẹ ko wọn igba kilogiraamu (200kg).
Wọn lawọn tun ba awọn ọmọbinrin kan, Funmilọla, to jẹ ọmọọmọ iya agbalagba naa, ṣugbọn bo ṣe ri awọn agbofinro lo sa lọ, iya agba nikan ni wọn ri mu.
Wọn lọwọ irọlẹ ọjọ naa lawọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn ti fara pamọ sagbegbe naa pada ri i mu, wọn si fi pampẹ ofin gbe e ju sahaamọ wọn.
Bakan naa, wọn ni ni nnkan bii aago kan aabọ irọlẹ ọjọ Aje, ọwọ ba Abilekọ Tessy Matthew, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, ninu otẹẹli Rate, to wa l’Opopona Care, ni Guusu Akurẹ yii kan naa, ibẹ ni wọn loun ti n ta egboogi oloro Skuchies fawọn eeyan, wọn si ti fi pampẹ ọba mu un lọ. Nigba ti wọn n wadii ọrọ lẹnu ẹ ni wọn lo jẹwọ pe ọmọbinrin kan wa tawọn jọ n ṣiṣẹ rira ati tita ẹru ofin wọnyi, Blessing Adeṣida lo porukọ, awọn agbofinro si ti lọọ fi pampẹ ofin mu oun naa.
Kọmanda ajọ naa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Callys Alumona, ti sọ pe iwadii ti n lọ lori gbogbo wọn, wọn o si ni i pẹ foju bale-ẹjọ lati gba sẹria to tọ si wọn.