Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adari ẹgbẹ Oodua Peoples’ Congress (OPC), Iba Gani Adams, ti sọ pe ti ilọsiwaju tootọ yoo ba ba orileede Naijiria, awọn adari gbọdọ ṣetan lati mu atunṣe ba iwe ofin ti a n lo lọwọlọwọ.
Nibi aṣekagba Ọdun Oodua ọlọdọọdun, eyi to waye ni gbagede Ẹnuwa, niluu Ileefẹ, ni Gani Adams ti sọ pe ọdaran oloṣelu ti ko ni ifẹ Naijiria lọkan nikan ni yoo sọ pe ṣe ni ka lọ sinu idibo apapọ ọdun 2023 lai kọkọ wa ọna atunṣe si ofin ti ẹnu n kun yii.
Iba Gani Adams ṣalaye pe, “Atunṣe gbọdọ ba ofin orileede yii ko too di pe idibo ọdun 2023 maa waye. Emi o sọ pe ki wọn ma ṣeto idibo o, nitori ẹnikan ṣaa gbọdọ wa nipo aṣẹ lọdun 2023, ṣugbọn fun wa lati tẹsiwaju lorileede yii, a gbọdọ bẹrẹ iṣejọba agbegbe (Regionalism).
“Ti a ko ba ṣe bẹẹ, mo gbagbọ pe ko si ẹni ti a yan sipo yẹn ti yoo ṣaṣeyọri kankan pẹlu ofin ti a n lo yii.
“Buhari ti n lọ bayii, asiko perete lo ku to ni lati mu ayipada ba gbogbo nnkan to wa nilẹ yii. Ṣe ni ko pe awọn aṣofin ati awọn lameetọ ilu lati ṣatunṣe iwe ofin naa bii iru eyi ti a ni lọdun 1960 si 1963, ki orileede yii le tẹsiwaju.
“Lai ṣe bẹẹ, orileede yii le ma pẹ o, a ko nilo lati tan ara wa, lọwọlọwọ bayii, gbogbo nnkan lo ti dorikodo, ọrọ aje ti dẹnukọlẹ, aisi eto aabo n gbilẹ si i lojoojumọ, ẹru n ba awọn oludaṣẹ-silẹ, ko si ina mọnamọna, ko si nnkan amayedẹrun.
“Awọn ologun (military) fun wa ni ofin ti ko dara lọdun 1999, a ni lati mu atunṣe ba gbogbo rẹ ki nnkan too le ṣe deede lorileede yii, ti a ko ba ṣe bẹẹ, a ko gbọdọ da awọn to n sọ pe ki orileede yii pin lẹbi rara.
“Orileede yii n wọnu gbese lojoojumọ, ṣe la n yawo lati fi ṣejọba. Ida ọgọta ninu ida ọgọrun-un owo bọjẹẹti la maa ya, bijọba apapọ ṣe n yawo naa nijọba ipinlẹ n ya, ta lo waa fẹẹ san gbese yẹn?
“Awọn oloṣelu wa gbọdọ mọ nnkan ti wọn n ṣe, awọn kan n pariwo nipa ipo aarẹ ọdun 2023 lai jokoo sọrọ lori iṣoro orileede yii. Awọn oloṣelu ti sọ Naijiria di okoowo.
“Wọn gbọdọ gbe igbesẹ yẹn lọdun yii ko too di 2023. Ẹnikẹni to ba n sọ pe ka ma ṣatunṣe si ofin ilẹ wa, ọdaran oloṣelu ni, ko si nigbagbọ ninu ohun to dara nipa orileede yoo, to si n ṣọla ninu ifasẹyin awọn araalu”
Ninu ọrọ tiẹ, Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, gboriyin fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ OPC fun aṣeyọri ọdun naa, o si gbadura fun wọn.