Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Elizabeth Pascal lorukọ obinrin ti wọn ṣa pa yii, awọn Fulani darandaran la gbọ pe wọn kun un bẹẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹta, ta a ṣẹṣẹ mu yii, ni Moriwi, Oke-Agbẹdẹ, eyi to wa ni Iwoye-Ketu, nijọba ibilẹ Imẹkọ Afọn, Yewa.
Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe odo lobinrin naa n lọ lati pọnmi lagbegbe CAC, Moriwi, lo ba pade awọn Fulani naa lọna, wọn ko si wo o lẹẹmeji ti wọn fi sọ ike ori rẹ kalẹ, ti wọn bẹrẹ si i bu u ladaa. Wọn ko ro ti pe obinrin ni rara, wọn ṣaa naa to jẹ nibi ti wọn ṣa a si lo pari ẹ si, obinrin naa ko le da dide mọ to fi ku.
Nigba to yẹ ko ti de lati odo ti ẹnikẹni ko gburoo rẹ ni wọn wa a lọ sodo ọhun, nibẹ ni wọn si ti ri oku ẹ pẹlu ọgbẹ ada to jinlẹ nipakọ, ọrun, apa ati kaakiri ara rẹ.
Iṣẹ agbẹ ni Elisa bi wọn ṣe maa n pe e, n ṣe pẹlu ọkọ rẹ n’Iwoye, ṣugbọn obinrin naa ti ku iku ojiji bayii, wọn si ni ko si ẹya mi-in to bu u lada bẹẹ, awọn Fulani darandaran ni.