Monisọla Saka
Apo irẹsi bii ẹgbẹrun mẹta ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu ko ranṣẹ sawọn eeyan ipinlẹ Nasarawa, o ni ki awọn Musulumi fi sọdun Itunu Aawe.
Alakooso ẹgbẹ to n ṣe ipolongo fun Tinubu nipinlẹ naa, Yusuf Omaki, lo ṣe kokaari pinpin irẹsi ọhun niluu Lafia, lọjọ Ẹti, Furaide, opin ọsẹ yii. Bẹẹ lo rọ awọn ti wọn janfaani iresi yii pe ki wọn ma ṣe ta a, ki wọn lo o fun ohun ti awọn tori rẹ fun wọn.
O ni igbesẹ naa waye lati mu itura ba awọn eeyan, paapaa ju lọ, awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ. O fi kun un pe awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, awọn ẹlẹ́sìn awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni yoo janfaani irẹsi ẹgbẹrun mẹta naa.
Bakan naa lo rọ awọn eeyan lati yan ẹni to kunju oṣuwọn sipo, ki wọn si ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC lasiko idibo to n bọ yii.
Saaju ni wọn ti pin iru irẹsi yii kan naa nipinlẹ Kano lọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Irẹsi naa ni wọn ya awọran oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Hammed Tinubu si.
Ọpọlọpọ awọn olugbe ilu naa ni wọn n gba irẹsi ọhun ti wọn kọ ‘JAGABAN’ si kẹtikẹti.
Laipẹ yii kan naa lo fi ẹbun miliọnu lọna aadọta Naira ta awọn eeyan ti ina ṣe ni ijamba nipinlẹ Nasarawa lọrẹ.