Bo ti ku dẹdẹ ki ọdun 2020 yii pari ni obinrin oniṣowo kan, Chirsty Mmakwe, pade iku ojiji, nigba ti ọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan ka a mọnu ṣọọbu ẹ, to si gun un lọbẹ lọrun.
Adugbo kan ti wọn n pe ni Alaba Rago, nipinlẹ Eko, ni iṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii. Bẹẹ la gbọ pe ọkunrin janduku kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Usman Shefiu, ni wọn fura si gẹge bii ẹni to ṣe ẹmi obinrin naa lofo.
Ọkan lara awọn eeyan agbegbe ọhun to ba oniroyin sọrọ sọ pe, ninu ṣọọbu lobinrin yii wa nigba ti Shefiu wọle lọọ ba a, bii ẹni to fẹẹ ra ọja lọwọ ẹ.
O ni ko pẹ to wọle ọhun lobinrin yẹn sare jade, to n pariwọ ‘ẹ gba mi’, bẹẹ ni ẹjẹ n tu jade lọrun ẹ, ti awọn eeyan si sare si i.
Faruk Ishọla, ọkan lara awọn eeyan to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe nibi ti wọn ti n gbe obinrin naa lọ si ọsibitu lo ti dakẹ mọ wọn lọwọ.
ALAROYE gbọ pe ninu sọọbu ẹ nibẹ lobinrin ti wọn pe ni ẹni ọgbọn ọdun yii atawọn ọmọ ẹ n gbe, ati pe ko ṣeni to le sọ pato ohun to da wọn papọ, ti Shefiu fi gun un lọbẹ lọrun.
Ileewosan kan ti wọn pe ni Kiladejọ Private Hospital, ni wọn sare gbe e lọ, ṣugbọn awọn yẹn sọ fun wọn pe ọsibitu jẹnẹra to wa ni Igando ni ki wọn yara maa lọ, ṣugbọn ti ẹlẹmi gba a ki wọn too gbe e debẹ.
Farouk ni bi wọn ṣe n du emi obinrin naa, bẹẹ lawọn eeyan kan ni adugbo ọhun ti sare le ọkunrin to gun un lọbẹ lọrun yii mu, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa l’Ekoo, Muyiwa Adejọbi, ti sọ pe loootọ lawọn araadugbo ọhun ti fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti, ati pe awọn ẹṣọ agbofinro ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iwadii wọn lori iṣẹlẹ ọhun bayii.
O ni wọn ti gbe oku Christy, ẹni ọgbọn ọdun, ọhun lọ siluu ẹ, nibi ti wọn ti lọọ sin in.