Ọga ileewe ti wọn fẹṣun kan pẹlu Sẹnetọ Adeleke ni ki ile-ẹjọ da ẹjọ naa nu l’Abuja

Eeyan mẹrin ti wọn fẹsun kan pẹlu Sẹnetọ, Ademọla Adeleke, ẹni to dije dupo gomina nipinlẹ Ọṣun, ni wọn ti bẹ ile-ẹjọ bayii pe ko da ẹjọ ọhun nu, ki awọn le sinmi a n waa jẹjọ ni kootu.

Awọn mẹrin ti wọn n bẹbẹ nile-ẹjọ ọhun ni Sikiru Adeleke, ẹni ti i ṣe ibatan Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ọga ileewe girama Ojo-Aro,  Alhaji Arẹgbẹṣọla Muftau; akọwe agba fun ileewe naa, Gbadamọsi Ojo; ati tiṣa kan ninu ileewe ̀ọhun, Dare Samuel Olutọpẹ.

Awọn agbẹjọro awọn eeyan mẹrẹẹrin yii sọ niwaju adajọ niluu Abuja pe gbogbo ẹri ti wọn ko siwaju ile-ẹjọ ọhun lati fidi ẹ mulẹ pe wọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ni ko lẹsẹ nilẹ rara.

Wọn ti waa rọ Adajọ Inyang Ekwo ko fọwọ si ẹbẹ ti awọn n bẹ bayii, niwọn igba ti ẹri tawọn alatako marun-un ti wọn ko wa ko ti fẹsẹ mulẹ kankan.

Lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii, ni ile-ẹjọ yọ orukọ Sẹnetọ Ademọla Adeleke kuro ninu iwe ipẹjọ onikoko meje ti wọn gbe lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bii ẹbẹ ti olupẹjọ, Ọgbẹni Simon Lough, bẹ niwaju adajọ.

Ọkunrin to duro bii olupẹjọ, Simon Lough, sọ pe aiwa sile-ẹjọ Adeleke le mu ki ẹjọ naa lọra nilẹ, paapaa niwọn igba ti ko ti si ni Naijiria latigba diẹ sẹyin. Wọn ni ohun to mu adajọ gba ẹbẹ ẹ niyẹn, ti wọn si yọ orukọ ẹ kuro, to waa ku awọn mẹrin ti wọn sọ pe wọn lọwọ si ẹsun eru esi idanwo ti wọn fi kan oludije fun ipo gomina Ọṣun ọhun, Ademọla Adeleke.

ALAROYE gbọ pe latijọ ti adajọ ti fun Sẹnetọ yii lanfaani lati lọọ tọju ara ẹ loke okun ni ko ti wa sile-ẹjọ mọ, ilu Amẹrika lọkunrin oloṣelu ọmọ Ẹdẹ yii gba lọ, ti awọn ti wọn fẹsun kan pe wọn ran an lọwọ si n paara kootu ni tiwọn.

Lọjọ ti Adeleke bẹbẹ ni kootu pe ara oun ko ya rara, oun nilo itọju to peye ni Amẹrika, oṣu kan pere ni wọn fun un, iyẹn laarin ọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun 2019, si ọjọ keje, oṣu kẹfa, ọdun kan naa, ṣugbọn latijọ ti ọkunrin yii ti ri baaluu wọ lọ si Amẹrika ni ko ti wa sile-ẹjọ mọ.

Tẹ o ba gbagbe, ẹsun ti wọn fi ko wọn lọ sile-ẹjọ ni pe ọga ileewe ọhun atawọn meji yooku lọwọ si iwa eru ṣiṣe ninu idanwo. Wọn ni awọn ni wọn forukọ Sẹnetọ Ademọla Adeleke ati Sikiru Adeleke silẹ gẹgẹ bii ọmọleewe Ojo-Aro Community Grammar School, fun idanwo NECO to waye ninu oṣu kẹfa si ikeje, ọdun  2017.

Wọn ni lẹyin ti wọn forukọ awọn eeyan yii silẹ tan ni wọn wa awọn eeyan kan ti wọn ba wo jokoo ṣe idanwo ọhun , eyi to lodi si ofin.

Awọn agbẹjọro wọn, Nathaniel Oke (SAN), Abdulfatai Abdusallam, ati Adegbitẹ Isaac, sọ niwaju adajọ pe ki wọn da ẹjọ ọhun nu, nitori ko si ẹri kan gboogi to fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn huwa ọdaran ọhun.

Bakan naa ni wọn sọ pe ko si ẹlẹrii kankan lati ajọ NECO to waa jẹrii ta ko wọn lori ẹsun ọhun.

Adajọ Ekwo ti sọ pe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, loun yoo gbe idajọ oun kalẹ.

 

Leave a Reply