Ọgbọn, imọ ati oye oṣelu ti mo kọ lọdọ Buhari lo jẹ ki n ṣaṣeyọri nipo gomina-Fayẹmi

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti sọ fawọn ọmọ ipinlẹ naa pe ki gbogbo wọn fọwọ sọwọ pọ pẹlu gomina tuntun to fẹẹ gba ipo lọwọ oun, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji, ki ere ijọba awa-ara-wa nipinlẹ naa le kari titi de ẹsẹ kuku

Fayẹmi ṣalaye pe gbogbo eeyan, ni pataki ju lọ, nipinlẹ Ekiti, gbọdọ sọwọ pọ mọ ijọba pẹlu ootọ inu ati ọkan kan, ki itẹsiwaju le de ba awujọ lapapọ.

Gomina pe ipe yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu yii, lasiko eto kan ti wọn gbe kalẹ lati ṣe isin ati idupẹ fun ọkunrin to fẹẹ fipo silẹ naa. Eto ọhun to waye ni gbọngan Ọbafẹmi Awolọwọ, l’Ado-Ekiti, ni gbogbo ọmọ ipinlẹ naa wa.

O sọ pe inu oun dun gidigidi bi awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ṣe n gbe oṣuba nla fun oun ati iyawo oun lakooko ọdun mẹrin ti oun fi wa lori ipo gẹgẹ bii gomina ipinlẹ naa. O ṣalaye pe idi pataki ti oun fi darapọ mọ oṣelu ṣiṣe ni lati le mu atunṣe ba awọn ohun to ti bajẹ, ati lati le jẹ ki orilẹ-ede Naijiria di atunbi lapapọ.

O juwe aṣeyọri rẹ nipo gomina gẹgẹ bii ọgbọn, imọ ati oye ti o ti ri kọ nibi oṣelu ṣiṣe, ni pataki ju lọ lọdọ Arẹ Mohammadu Buhari, Oloogbe Anthony Ẹnahoro, Ọjọgbọn Wole Ṣoyinka ati Oloye Odigie Oyegun pẹlu awọn olori orile-ede Naijiria tẹlẹ miiran.

O fi kun un pe inu oun dun gidigidi pe oun ṣejọba nipinlẹ Ekiti gẹgẹ bii Apọọsu Pọọlu ṣe sa ere ije ninu Bibeli, ti oun si mu ayipada ba gbogbo ẹka iṣejọba nipinlẹ naa.

Fayẹmi dupẹ gidigidi lọwọ awọn gomina ẹlẹgbẹ rẹ ati awọn ẹka iṣejọba apapọ, to fi mọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ekiti fun ṣiṣe atilẹyin foun.

Gomina ni o da oun loju pe gomina to fẹẹ gba ipo lọwọ oun, Ọgbẹni Biọdun Oyebanji, yoo ṣe ohun gbogbo lati tẹsiwaju pẹlu eto ti oun gbekalẹ l’Ekiti, gẹgẹ bii Timotiu ninu iwe mimọ Bibeli.

O ṣeleri pe atunṣe ati itẹsiwaju yoo de ba orile-ede Naijiria, o fi kun un pe bi oun ṣe n kuro lori ipo gomina ipinlẹ Ekiti ko da oun duro lati maa gbe eto ti yoo mu ayipada rere ba ipinlẹ naa ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

 

 

Leave a Reply