Ọlawale Ajao, Ibadan
Niṣe lọrọ adari ṣọọṣi kan n’Ibadan, Adebayọ Bamidele, da bii igba teeyan ba fori jona, to si gbóòórùn ara ẹ pẹlu bo ṣe fẹsun iwa ọdalẹ kan iyawo ẹ, Felicia Bamidele, ni kootu ibilẹ Ọja’ba to wa ni Mapo, n’Ibadan, ti iyẹn si tu gbogbo aṣiri iwa ibajẹ to (pasitọ) n hu pata loju gbogbo aye.
Pasitọ Bamidele, ẹni to pẹjọ lati kọ Felicia silẹ ni kootu ọhun lọjọ Aje, Mọnde, to kọja, ṣapejuwe iyawo ẹ gẹgẹ bii alákòóbá obinrin nitori bo ṣe dina ijẹ mọ oun pẹlu bo ṣe kọyin oun atawọn ọmọ ijọ oun sira awọn, eyi to mu ki awọn eeyan naa dawọ jọ lu oun laipẹ yii.
O ṣalaye pe “Pasitọ ṣọọṣi ni mi. Ṣugbọn iyawo mi ti dina ijẹ mi. A jo da ijọ silẹ ni, ṣugbọn nigba to ya lo n sọ fawọ̣n ọmọ ijọ pe pasitọ lasan lemi jẹ ninu ijọ wa, oun (iyawo) gan-an loludadilẹ ijọ.
“Lọjọ kan lo tun ṣẹsin ni ṣọọṣi, lo ba n pariwo pe ‘ẹ ma gbà á (pasitọ) gbọ́ o, ogo yin lo n lo o’. Nnkan to fi ba temi jẹ gan-an niyẹn nitori niṣe lawọn ọmọ ijọ dawọ jọ le mi lori lọjọ yẹn, ti wọn bẹrẹ si i na mi. Ka pe mi o tete ja ara mi gba mọ wọn lọwọ ki n sa lọ ni, boya lọjọ̣ ni mi o ba raye mọ nitori wọn ò sọ pawọn o lu mi pa.”
O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si ibaṣepọ to wa laarin oun ati Felicia.
Ṣugbon niṣe lo da bii ẹni pe pasitọ yii fori jona, to si gbóòórùn ara ẹ pẹlu bi iyawo ẹ ṣe sọ fun igbimọ awọn adajọ pe oun fara mọ ki wọn tu igbeyawo ọhun ka gẹgẹ bi ọkọ oun ṣe fẹ, ṣugbọn oun fẹ kile-ẹjọ mọ pe ọdaran pọnbele lọkunrin naa, ko si yẹ lẹni ti iba maa dari ijọ Ọlọrun rara.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Emi ni mo ni ṣọṣọṣi loootọ, nitori emi ni mo kowo ta a fi kọ ṣọọṣi silẹ. Ẹẹmeji ni mo kowo yẹn kalẹ, mo kọkọ ko ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,000) silẹ, ki n too tun ko ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira (N30,000) silẹ.
‘‘Ogo mi lo n lo. O maa n bu kinni lubulubu kan bii iyọ sinu beba fun mi pe ki n fi i sabẹ irọri mi ti mo ba fẹẹ sun lalẹ. Nigba to ya ni mo ri i lójúran pe ogo mi lo n lo.
“Iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ nibi ta a ti n ṣeto itusilẹ ni ṣọọṣi lọjọ kan lo taṣiiri ẹ le mi lọwọ. A n ṣe itusilẹ ni ṣọọṣi lọjọ kan ni iji nla kan deede bẹrẹ si i ja. Mi o mọgba ti mo ba ara mi nilẹ, mi o mọ nnkan naa to gbe mi ṣubu.
Ṣugbọn kaka ki ọkọ mi sun mọ mi lati waa gbe mi dide, o kan n wò mi bọ̀ọ̀ nilẹ bayii ni. Gbogbo bi mo ṣe n pe e to, ko tiẹ da mi lohun. Iṣẹlẹ yẹn lo sọ mi di ẹni to rọ lapa, rọ lẹsẹ.
“O (ọkọ ẹ) fun mi ni adiẹ kan pe ki n fi pa apa ati ẹsẹ mi to rọ. O ni lẹyin naa, ki n ju adiẹ yẹn sita. Ṣugbọn kaka ki apa ati ẹsẹ yẹn pada si bo ṣe wa tẹlẹ, o tubọ n rọ si i ni. Pasitọ mi-in lo pada tọju mi ti mo fi gbadun.
“Iyẹn ko tiẹ waa dun mi bii isọnu ati itiju to mu ba oluwa rẹ nitori nigba ti mo ju adiẹ yẹn sita bayii, niṣe lo n fò lọ titi to fi lọọ bà sinu ile onile. Awọn onile ba bẹrẹ si i pariwo le mi lori pe ogun ni mo ran sinu ile awọn.”
O waa rọ ile-ẹjọ lati pa olupẹjọ laṣẹ lati da owo ti oun (iyawo) ko silẹ fun un (ọkọ) lati da ijọ silẹ pada foun.
Gẹgẹ b’akọroyin wa ṣe gbọ, ibaṣepọ awọn mejeeji ko lọmọ ninu. Lẹyin ti ọkọ aarọ Felicia ku lo fẹ Bamidele. Pasitọ paapaa ti fẹyawo kan ri tẹlẹ, iyẹn si ti bimọ fun un ki wọn too kọra wọn silẹ.
Ile-ẹjọ ti tu igbeyawo naa ka. Oloye Ọdunade Ademọla ti i ṣe olori igbimọ awọn adajọ kootu naa sọ pe oun ko le ṣedajọ kankan lori ọrọ gbese ti Felicia sọ pe Bamidele jẹ oun. O ni ṣe lo ni lati pẹjọ mi-in lọtọ lori ọrọ onigbese de yii.