Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọgọfa eeyan ni wọn lo ti ko arun Korona laarin ọjọ kan ṣoṣo nipinlẹ Ondo. Gẹgẹ bi atẹjade ti igbimọ to n mojuto ajakalẹ arun Covid 19 fi sita, ipinlẹ Ondo lo ṣaaju awọn ipinlẹ mọkandinlogun ti wọn ti ṣe akọsilẹ awọn eeyan to lugbadi arun Korona lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nikan.
Apapọ iye awọn to ko arun ọhun ni wọn lo to bii okoolelẹẹẹdẹgbẹta (520).
Ọgọfa lawọn to ko arun naa nipinlẹ Ondo, mọkanlelogun ni ti ipinlẹ Borno, Ebonyi ni mẹtadinlogoji, Benue ni mẹtalelògbọn, ti ipinlẹ Plateau si ni ọgbọn. Abuja, mọkandinlọgbọn, Nasarawa ati Ogun, marundinlọgbọn, Edo ati Ọsun, mẹrinlelogun, Katsina mejilelogun, Kaduna mọkanlelogun, Niger Ogun, Kwara mẹrinla, Ekiti, mẹtala, Yobe, mẹwaa, Ọyọ, mẹrin, nígbà ti Bayelsa àti Jigawa ni ẹyọ kan.
Eyi n waye lẹyin ọsẹ kan tawọn dokita ijọba ti bẹrẹ iyansẹlodi latari aabọ owo-osu kọkanla ọdun to kọja tijọba Gomina Rotimi Akeredolu san fawọn oṣiṣẹ.