Irọ lawọn ọlọpaa n pa, a ko ba wọn já ti ọga wọn fi yinbọn mọ wa l’Orílé-Igbọ́n – Ọga Amọtẹkun

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

 

Gbogbo ẹni to gbọ nipa bi ọga ọlọpaa kan niluu Orílé-Igbọ́n, nitosi Ògbómọ̀ṣọ́ ṣe yinbọn mọ oṣiṣẹ ẹṣọ Àmọ̀tẹ́kùn kan niṣẹlẹ ọhún n ṣe ni kayeefi.

DPO, ìyẹn ọga ọlọpaa teṣan Orílé-Igbọ́n, nijọba ibilẹ Surulere, nitosi Ògbómọ̀ṣọ́, nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ayọdeji Adepọju, ni wọn lo yinbọn mọ oṣiṣẹ Amọtẹkun naa lọjọ Ẹtì, Furaidee, to kọja yii.

Awijare awọn ọlọpaa ni pe ẹṣọ Amọtẹkun agbegbe naa ni wọn mura ìjà waa ba awọn ni teṣan lẹyin ti wọn ti gbiyanju lati dana sun oko olókó, ṣugbọn ti awọn kò gba fún wọn láti ṣe bẹẹ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ṣaaju ni DPO yii ti fi panpẹ ọba gbe meji ninu awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun wọnyi nitori afurasi ọdaran Fúlàní kan.

Awọn Fúlàní yii ni wọn fi maaluu jẹ oko oloko lájẹbàjẹ́ labule Gambari, lẹgbẹẹ Ògbómọ̀ṣọ́, ti awọn ẹṣọ Amọtẹkun fi mu wọn lẹyin ti olókó lọọ fẹjọ wọn sun eeyan naa.

Eyi ni ko dun mọ awọn ẹlẹgbẹ Fúlàní wọnyi ninu ti wọn fi lọọ fẹjọ awọn Amọtẹkun sun lagọọ ọlọpaa to wa l’Orile-Igbọn.

Wọn ni niṣe lọga ọlọpaa teṣan náà gbina jẹ, o ni ijọba ko da Amọtẹkun silẹ lati maa mu awọn Fúlàní darandaran, bi ko ṣe lati máa mú àwọn adigunjale. N lo ba paṣẹ fawọn ọlọpaa abẹ ẹ lati mu awọn Amọtẹkun to mu awọn bàsèjẹ́ Fúlàní naa wa foun kiakia.

Nigba ti ọga awọn Amọtẹkun agbegbe naa, Ọgbẹni Araoye Amọo, dé teṣan ọ̀hún lati gba awọn ọmọ ẹ silẹ lọrọ ba ọna mi-in yọ nigba ti awọn ọlọpaa yinbọn, ti wọn sì mu mẹta ninu wọn ti mọle.

Wọn ni nibi ti Araoye ti n ba awọn ọlọpaa to wa laaye igbalejo ni teṣan naa sọrọ lọwọ ni DPO ti jade wa lati ọfiisi ẹ nitori to n gbọ ohùn wọn, to si gba ibọn lọwọ ọkan nínú awọn ọlọpaa abẹ ẹ̀, tó yín in mọ ọkan ninu awọn ẹṣọ Amọtẹkun lai beṣu-bẹgba.

Oludari ikọ Àmọ̀tẹ́kùn ni ipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju fidi ẹ mulẹ pe “Ẹsẹ nibọn ti ba ẹni tí wọn ṣe lè ṣe yẹn, a si ti gbe e lọ sileewosan LAUTECH, nílùú Ògbómọ̀ṣọ́ fún ìtọ́jú.

Ninu atẹjade to fi ṣọwọ́ sawọn oniroyin n’Ibadan, Agbẹnusọ fún ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi sọ pe nitori pe awọn ẹṣọ Àmọ̀tẹ́kùn mura lati ba awọn ọlọpaa já ni rogbodiyan ọhun ṣe waye. Ṣugbọn kò sọ pé ọlọpaa yinbọn mọ ẹnikẹni ninu atẹjade naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Akọwe ẹgbẹ Miyetti Allah, ìyẹn, ẹgbẹ àwọn Fúlàní darandaran, Alhaji Oroji Allah, lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Orílé-Igbọ́n, pe awọn Amọtẹkun fẹẹ dáná sun oko awọn.

“Awọn ọlọpaa lọọ mu àwọn Amọtẹkun yẹn lọ sí teṣan wọn láti ba wọn yanju ọrọ yẹn nítùbí-ǹ-nùbí.

Ọrọ yẹn ni wọn n yanju lọwọ ti awọn Amọtẹkun bíi ọgbọn (30) fi ya dé teṣan yẹn tijatija.

Ọwọ ọlọpaa tẹ mẹta ninu wọn. Ééríá Kọ̀mandà (ọga ọlọ́pàá agbegbe Ogbomoṣọ) ti n tẹsiwaju nínú ìwádìí lori iṣẹlẹ yẹn”.

Ṣugbọn Ọgbẹni Araoye ti i ṣe ọga awọn Amọtẹkun agbegbe naa ṣọ pe irọ pata lawọn ọlọpaa n pa nipa iṣẹlẹ yii.

O ni, “A ò ba tìjà lọ sí teṣan yẹn rara. Nitori ẹ̀ la ṣe rí i daju pe kò sí ọta kankan ninu gbogbo ibọn ta a gbe lọ síbẹ. Lati waa ṣọ pe ara ija la mu lọ síbẹ̀, irọ pata ni. Awọn gan-an yẹ awọn ibọn ti wọn gba lọwọ àwọn èèyàn wa ti wọn ti mọle wo, wọn rí i pe ko sí ọta kankan ninu wọn. ”

 

 

 

Leave a Reply