Faith Adebọla
Pẹlu bijọba Naijiria ṣe n sapa lati ko awọn ọmọ Naijiria ti ogun to n lọ lọwọ nilẹ Ukraine ka mọ pada wale, o kere tan, awọn genge ati obinrin marundinlọgọfa (115) ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ni wọn lọọ forukọ silẹ nileeṣẹ aṣoju ilẹ Ukraine, niluu Abuja, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹta yii, wọn lawọn ṣetan lati lọ si Ukraione ni tawọn, wọn lawọn yọnda ara awọn fun ogun jija, awọn fẹẹ gbeja orileede Ukraine ta ko akọlu tilẹ Russia n ṣe si wọn.
Ṣibaṣiba lẹsẹ awọn ọdọ naa pe si Ẹmbasi orileede Ukraine, l’Abuja, latari bi Aarẹ ilẹ naa, Volodymyr Zelensky, ṣe kede lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, pe awọn n wa awọn ọdọ kaakiri agbaye ti wọn nifẹẹ ilẹ Ukraine, ti wọn si le yọnda ara wọn lati ba a jagun lodi si Russia.
Bawọn ọdọ naa ṣe de Ẹmbasi Ukraine ni wọn ti lọọ forukọ silẹ ninu rẹjista kan ti wọn ṣi silẹ fawọn to fẹẹ yọnda ara wọn fun ogun jija ọhun, ṣugbọn awọn agbofinro ko jẹ kawọn oniroyin ya fọto oju awọn ọdọ naa.
Akọwe Ẹmbasi Ukraine, Bohdan Soltys, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loootọ lawọn ọdọ naa lawọn fẹẹ gbeja orileede Ukraine, wọn si n pọ si i, ṣugbọn awọn o ti i bẹrẹ eto lati ko wọn lọ, tori o lawọn iwe adehun ati igbesẹ tawọn alaṣẹ Ukraine ati ti Naijiria gbọdọ ṣe, ki wọn too lọ.
Aarẹ Ukraine ti sọ pe gbogbo eto to yẹ lawọn maa ṣe fẹnikẹni to ba fẹẹ waa ran awọn lọwọ ninu akọlu to n lọ lọwọ ọhun.