Iku ti i wọle adun ti i sọ ọ di kikan lo wọle idile ọkunrin ti ẹ n wo yii, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ David Gbodi Odaibo, nitori David ṣẹṣẹ jẹ ẹbun owo nla, biliọnu mọkandinlaaadọrin owo naira, eyi ti i ṣe ọgọfa aabọ dọla (125$) niluu oyinbo ni, afi bo ṣe jẹ pe ọjọ keje to jẹ owo ọhun niku de.
Ọmọ Naijiria ni Oloogbe David Gbodi, ṣugbọn ilu oyinbo lo n gbe, Ogbontarigi amojuẹrọ ni, iṣẹ naa lo ṣe fun wọn lọhun-un, to jẹ ki wọn mọ awọn apẹẹrẹ ti wọn yoo ri ti ijamba ba fẹẹ ṣẹlẹ ni papakọ ofurufu, ohun to jẹ ki wọn fun un niṣẹ olowo gọbọi naa ree nibi kan ti wọn n pe ni Homeland Security.
Ọsẹ kan lẹyin ti aṣeyọri nla yii wọle fun un ni David sun ti ko ji mọ. Ẹgbọn rẹ, Stephen Gbodi, ṣalaye pe aisan ọkan ti wọn n pe ni ‘Heart attack’ lo ṣe aburo oun lojiji.
O ni ki i ṣe Korona lo pa a, nitori o tiẹ ti gba abẹrẹ to n dena arun naa, o wulẹ wu iku ko ṣiṣẹ ọwọ rẹ nile awọn ni.
O ni awọn obi awọn mejeeji ṣi wa laye, David niyawo kan ati ọmọ meji, bẹẹ lo fi awọn ọmọ iya rẹ mẹrin silẹ lojiji yii.
“Bi o ba ṣi n ri eeyan rẹ nitosi, ti awọn to o fẹran ṣi wa ni arọwoto rẹ, dakun, fifẹ han si wọn lonii, di mọ wọn, jẹ ki wọn mọ pe o fẹran wọn. Nitori ẹni ta a jọ ṣode ana, o le dọla ka ma ri i mọ.” Bẹẹ ni ẹgbọn Oloogbe David gba awọn eeyan nimọran.