Ọjọ keji igbeyawo lọkọ ku sinu ijamba ọkọ, iyawo naa ko ti i laju lọsibitu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọ eeyan lo ku, nigba tawọn mi-in tun fara pa yannayanna ninu ijamba ọkọ kan to waye lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni Apọnmu, nitosi Akurẹ.  Akọroyin wa fidi rẹ mulẹ lasiko to ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa pe awakọ bọọsi elero mejidinlogun kan  ti wọn porukọ rẹ ni Dele ni wọn lo n bọ lati ilu Eko, to si fẹẹ lọọ ja awọn ero to wa ninu ọkọ rẹ silẹ l’Akurẹ ko too tun pada siluu Ondo, nibi to n gbe.

Bo ṣe ku diẹ ko de ori afara kan to wa ni iyana Apọnmu, eyi ti ko ju bii ibusọ marun-un pere mọ ko wọ igboro Akurẹ lo pade ọkọ ajagbe kan lojiji to yiwọ ṣoju ọna to yẹ ko gba kọja.  Ibi to ti n gbiyanju ati ya fun tirela naa lo ti ṣeesi ko sinu omi nla kan to wa labẹ afara naa.  Eeyan marun-un pere lawọn ẹsọ oju popo ri ko lọ sile-iwosan laaye ninu gbogbo ero to wa ninu ọkọ ọhun.  Ibi tí wọn ti n gbiyanju ati fi aake sa ọkọ naa ki wọn le ri oku awọn to ha mọ inu rẹ fa jade ni akọroyin ALAROYE fi wọn si ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ yii.

Lara awọn to fara gba ninu ijamba ọkọ ọhun ni tọkọ-taya kan ti wọn ṣẹṣẹ ṣegbeyawo lọjọ Abamẹta, Satide ọsẹ to kọja, loju ẹsẹ lọkọ ti ku, ti iyawo rẹ si wa lẹṣẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ, gbogbo ẹru iyawo wọn la ri to fọn kaakiri inu igbo ti iṣẹlẹ yii ti waye.

Leave a Reply