Faith Adebọla, Eko
Inu ọfọ ati ibanujẹ nla ni awọn mọlẹbi ati ọrẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Dele Bandele wa bayii, latari bi ireti wọn lati ri Dele ti wọn kọkọ ro pe o sọnu ni, ṣe ja si pabo, oku ọmọkunrin naa ni wọn pada ri.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mọkanla owurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn ti n wa oloogbe ọhun, tori o ti to bii wakati mẹrin ti wọn ti ri i kẹyin nigba yẹn.
Adugbo Ọmọle Phase 2, lọmọkunrin naa n gbe, owurọ ọjọ Iṣẹgun ni wọn lo loun n lọ si Isalẹ Eko, iwadii si fihan pe itosi afara Third Mainland Bridge lawọn kan ti kofiri ẹ kẹyin, eyi lo mu ki wọn kede pe o ti sọnu.
Ọrẹ rẹ kan to porukọ ara ẹ ni Sunkanmi ba akọroyin wa sọrọ lori aago, o ni gbogbo ọsan ọjọ Iṣẹgun naa titi tilẹ fi ṣu lawọn fi wa Dele, ṣugbọn ti ko sẹni to jọ ọ, bẹẹ lawọn sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa. Bilẹ ọjọ keji, Wẹsidee, ṣe mọ lawọn tun ti ko sẹnu ẹ.
Sunkanmi ni afi bo ṣe di nnkan bii aago kan ọsan ti iroyin gbode pe wọn ti ri oku ẹ, wọn ni afaimọ ko ma jẹ pe niṣe lo pa ara ẹ.
Idi ni pe ọrọ to kọ kẹyin sori ikanni ayelujara ẹ ni pe aye ti su oun, ọdun keje ree toun ti n ni ẹdun ọkan loriṣiiriṣii, ti gbogbo ẹ si ti toju su oun, o laye oun ko wu oun mọ, oun o si fẹran ara oun mọ, bo tilẹ jẹ pe oun mọ pe awọn eeyan kan fẹran oun.
O loun mọ pe iku oun maa ja wọn kulẹ, ki wọn jọọ, foriji oun, ki wọn si gbadura foun, oun n lọ.
Ninu ọrọ to fi kadii akọsilẹ naa, Oloogbe Dele ni: “Mi o le kọ lẹta si mama mi nipa ohun ti mọ fẹẹ ṣe yii, mi o to bẹẹ, iyẹn lẹ maa fi mọ bi mo ṣe nifẹẹ iya mi to. Ni ti baba mi, mo gbadura pe k’Ọlọrun dariji wọn, mi o ni i sọ ju bẹẹ lọ. Gẹgẹ bi mo ṣe maa n sọ, ile aye da bii ẹni n ṣe pati ni, bi pati naa ko ba dun mọ, keeyan fopin si i lo daa.”
A sapa lati ba Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ nipa iṣẹlẹ yii, ṣugbọn ko ti i dahun ipe wa titi ta a fi ko iroyin yii jọ.