Christianah to gba ẹru ole l’Ekiti ti dero kootu

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Obinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Christianah Afuyẹ, ti dero kootu ilu Ado-Ekiti lori ẹsun gbigba ẹru ti wọn ji lagọọ ọlọpaa niluu Ikẹrẹ-Ekiti.

Alaye ti Inspẹkitọ Oriyọmi Akinwale ṣe ni pe loṣu kọkanla, ọdun to kọja, lobinrin naa gba tẹlifiṣan LG kan lọwọ Toyin Ọlaoye, eyi to jẹ ọkan lara awọn ẹru tawọn janduku ko nigba ti wọn kọ lu teṣan ọlọpaa to wa ni Anaye, n’Ikẹrẹ-Ekiti.

Ẹṣẹ yii lo ni o ta ko ofin iwa ọdaran Ekiti, bẹẹ lo beere fun aaye lati ṣagbeyẹwo ọran naa daadaa kawọn ẹlẹrii le wa si kootu.

Christianah ni oun ko jẹbi nigba tọrọ kan an, bẹẹ ni Amofin Gbenga Ariyibi bẹbẹ fun beeli ẹ.

Lẹyin agbeyẹwo iwe ẹsun naa, Majisreeti-agba Lanre Owolẹṣọ fun olujẹjọ ni beeli ẹgbẹrun marundinlọgọrin naira (N75,000) ati oniduuro meji. O ni ọkan ninu wọn gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba onipele kẹẹẹdogun soke to ni iwe owo-ori ọdun mẹta.

Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu to n bọ, nigbẹjọ yoo tun waye.

 

Leave a Reply