Ojo yii yoo pẹ lẹwọn o, iyawo oniyawo lo fipa ba lo pọ l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majistreeti Ado-Ekiti ti fi ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan torukọ ẹ n jẹ Abiọdun Ojo, sẹwọn titi di ọjọ keji, oṣu kẹsan-an, ti igbẹjọ rẹ yoo maa tẹsiwaju, wọn lo fipa ba iyawo oniyawo lo pọ ni.

Ogunjọ, oṣu keje, ọdun 2021 yii, ni wọn ni Ojo fipa ba obinrin kan to wa nile ọkọ lo pọ, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn lobinrin ọhun gẹgẹ bi Agbefọba, Inspẹkitọ Caleb Leramo, ṣe ṣalaye fun kootu naa nigba to n ṣoju ijọba lọsẹ to kọja yii.

Agbefọba rọ kootu pe ki wọn ṣi fi Ojo pamọ sẹwọn titi toun yoo fi gba imọran lati ọdọ ẹka to n gba kootu nimọran lori ẹsun bii eyi. Atotonu ti afurasi to n jẹjọ naa si ṣe lati ta ko eyi ko ta leti adajọ rara.

Adajọ Mojisọla Salau to gbọ ẹsun naa  paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ sẹwọn titi digba ti imọran yoo fi de, ibẹ ni yoo wa titi di ọjọ keji, oṣu kẹsan-an 2021.

Leave a Reply