Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni awọn alaṣẹ Fasiti Ilọrin, nipinlẹ Kwara, kede Ọjọgbọn Wahab Ọlasupọ Ẹgbẹwọle, (SAN) gẹgẹ bii giiwa agba tuntun ileewe naa.
Alaga igbimọ Fasiti Ilọrin, Malam Abidu Yazid, (OON) lo kede iyansipo naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni gbọngan to wa ninu ọgba ileewe ọhun niluu Ilọrin, o ni, ‘Nibaamu pẹlu ofin ileewe naa ati ofin Naijiria, asiko to yẹ ki ọga agba to fẹẹ fipo silẹ yoo tẹnu bọpo ni ọjọ kẹẹẹẹdogun, osu Kẹwaa, ọdun 2022, ti ileewe naa si ti bẹrẹ igbesẹ yiyan ẹlomiran lati oṣu Kẹta, ọdun 2022, nipa kikede fun gbogbo aye pe ẹni to ba nifẹẹ si ipo naa ko kọ iwe mo n wa ipo’.
Wọn ni eeyan mẹrindinlọgọta (56), lo n wa ipo naa ki wọn too ja wọn ku mẹtala (13), lẹyin ti awọn igbimọ alaṣẹ ṣe ayẹwo finnifinni fun wọn fun odidi ọjọ mẹrin, ki ipo naa too ja mọ Ọjọgbọn Ẹgbẹwọle lọwọ.
Ẹni ọdun mọkanlelaaadọta ni ọga agba tuntun yii, to si gba oye imọ ijinlẹ ẹlẹkẹta (Ph.D. degree), ninu imọ ofin (Law and Jurisprudence), to si ti wa ninu Fasiti Ilọrin, lati bii ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin. Ni afikun, amofin agba (SAN), ni lorile-ede Naijiria.
Awọn alaṣẹ Fasiti Ilọrin, ki i ku oriire ijawe olubori rẹ ti wọn si ni wọn setan lati ba a ṣiṣẹ ko le ṣe aṣeyọri nibaamu pẹlu afojusun Fasiti Ilọrin.