Awọn kọsitọọmu gbẹsẹ-le ‘kinni’ kẹtẹkẹtẹ tawọn kan n ko lọ siluu oyinbo  

Monisọla Saka

Oriṣiiriṣii lọna lawọn eeyan wa n gba wa owo bayii, igbo, kokeeni atawọn egboogi oloro mi-in la mọ ti wọn n ko lọ soke okun fun tita, ṣugbọn ni bayii, oko kẹtẹkẹtẹ ni wọn tun n ko lọ siluu oyinbo, ko si sẹni to mọ ohun ti wọn fẹẹ lo o fun nibi ti wọn n ko o lọ.

Nnkan ọkunrin akọ kẹtẹkẹtẹ to to ẹgbẹrun meje lawọn kọsitọọmu papakọ ofurufu Murtala Mohammed, niluu Eko, gba lasiko ti wọn n gbe ẹru ofin naa lọ si orilẹ-ede China.

Sambo Dangaladima to jẹ olori awọn kọsitọọmu lagbegbe naa ṣalaye fawọn oniroyin pe inu  apo ṣakaṣaka mẹrindinlogun ni wọn ko nnkan ọkunrin kẹtẹkẹtẹ ọhun si, bẹẹ ni wọn si san igba miliọnu Naira o le diẹ (N216, 212, 813) gẹgẹ bii owo ẹru ọhun si.

Dangaladima ṣalaye pe oorun buruku to n jade latara awọn apo yẹn lo pe akiyesi awọn kọsitọọmu si i, eyi lo si mu kawọn sun mọ’bẹ lati beere nnkan ti wọn ko sapo to le maa mu iru oorun buruku bẹẹ jade.

“Irọ tawọn to fẹẹ ko ẹru naa lọ soke okun pa nigba ti wọn bi wọn leere ni pe ẹpọn maaluu lo wa nibẹ. Lẹyin ayẹwo to peye lawọn oṣiṣẹ mi ri i pe nnkan ọkunrin kẹtẹkẹtẹ ni. Igba akọkọ si ree ta a maa gba iru ẹru bayii silẹ.

A o ni i faaye gba iru owo bayii lakata wa”.

Ẹka ti wọn ti n yẹ ẹru wo ni papakọ ofurufu ọhun ti gbe apo ti wọn ko awọn nnkan ọkunrin akọ kẹtẹkẹtẹ yii si fun ileeṣẹ eleto ọgbin (Nigeria Agricultural Quarantine Service), ti igbakeji adari wọn, Adebimpe Adetunji, ṣoju fun.

Leave a Reply