Awọn ọmọ Hausa yii lọọ ji waya ina tu n’Ikoyi

Faith Adebọla, Eko

Marun-un ni wọn, Yẹkinni Mohammed, ẹni ọdun mejilelaaadọta, Mukaila Tukur, ẹni ọdun mejilelogoji, Abdulrazaq Abdulrahmon, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Mohammed Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, ati Nura Danladi, ẹni ọdun marundinlogoji,  iyẹn awọn ni afurasi adigunjale ti wọn lọọ ji waya in nidii tiransifọma laajin oru lagbegbe Ikoyi, nipinlẹ Eko, wọn si ti bọ sakolo ọlọpaa.

Ọga agba ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squard) ṣalaye pe lasiko tawọn ọlọpaa n yide kiri igboro loru ọjọ Ẹti, Furaidee, mọju Satide, ni wọn kẹẹfin awọn afurasi ọdaran naa ni nnkan bii aago meji aabọ.

Wọn ni bọọsi Volkswagen T4 kan to ni nọmba KTU 357 YF Lagos, ni wọn gbe wa, bawọn ọlọpaa ṣe yọ si wọn lojiji ni wọn ṣakiyesi pe awọn afurasi naa dọgbọn ra pala sabẹ mọto naa, wọn o mọ pe wọn ti ri wọn.

Nigba tawọn ọlọpaa si beere pe ki lawọn maraarun n wa kiri laajin oru, ede Hausa ni wọn n sọ, wọn lawọn o gbọ Yoruba, wọn o si gbọ oyinbo. Eyi lo mu kawọn agbofinro naa wo gbogbo ayika ọhun, ni wọn ba ri i pe awọn afurasi yii ti lọọ hu waya ribiti dudu ti wọn ri mọlẹ to muna lọ sidi ẹrọ amunawa agbegbe naa, wọn ge e, wọn si ka a lati wọ ọ sinu ọkọ wọn.

Nigba ti wọn de teṣan ọlọpaa, eyi to n jẹ Yẹkinni ninu wọn sọ pe oun ki i ṣe ara wọn o, onimọto loun, o ni Mukailu ati Abdullahi lo waa bẹ oun lọwẹ pe koun waa ba wọn fi mọto oun ko ẹru kan lati Ikoyi lọ si adugbo Lakulaku, l’Ọbalende, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, o nibẹ ni wọn ti fẹẹ ta waya naa fun kọsitọma to ti n duro de wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, ti ni ki wọn fi awọn afurasi naa ṣọwọ sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ to n tọpinpin iwa idigunjale, ki wọn tubọ ṣewadii, ki wọn si foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply