Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Iwaju Onidaajọ Idris Etsu, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni agbegbe Centre Igboro, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lawọn tọkọ-taya meji kan, Abilekọ Toyeebat AbdulSalam, ati Ọgbẹni AbdulSalam Toheeb, wọ ara wọn lọ. Toyeebat lo gbe ẹjọ ọkọ rẹ lọ sile-ẹjọ naa pe ki adajọ tu igbeyawo ọdun gbọọrọ to wa laarin awọn mejeeji ka, ki kaluku awọn le maa lọ layọ ati alaafia lọtọọtọ.
Ninu ọrọ rẹ nile-ẹjọ ọhun lo ti sọ pe, ‘‘Oluwa mi, inu mi maa dun gidi bẹ ẹ ba le tu igbeyawo ọdun gbọọrọ to wa laarin emi pẹlu ọkọ mi yii ka. Ẹmi mi ti fẹẹ pin, latigba ti mo ti bimọ akọkọ fun un ni wahala yii ti bẹrẹ, ojoojumọ, ija ni bii alafiṣe. Mo kọkọ lero pe yoo yi iwa rẹ pada ni titi ti mo fi bi ọmọ marun-un fun un, ṣugbọn ija naa ko duro, ṣe lo n peleke si i, Yoruba lo si maa n sọ pe kọrọ aye san ju kọrọ ọrun lọ. O ti su mi, mi o le fara da a mọ, Oluwa mi, ẹ ba mi tu igbeyawo naa ka ni kiakia.
“Gbogbo igbiyanju mi lati wa ọna abayọ si ija to n waye ọhun lo ja si pabo, emi o si fẹẹ ku bayii, ki ẹ tete pin gaari laarin awa méjèèjì”.
Olujẹjọ, AbdulSalam, ko yọju sile-ẹjọ lati wi awijare tiẹ, eyi lo mu ki Onidaajọ Idris Etsu sun igbẹjọ si ọjọ kẹtala, oṣu Kejika, ọdun 2024 yii.