Ojuṣe gbogbo ọmọ ilu ni lati ri i pe opopo Kwara mọ roro- Ijọba

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọruu Wẹsidee, ọsẹ yii, nijọba ipinlẹ Kwara sọ ọ di mimọ fun gbogbo tolori, tẹlẹmu nipinlẹ naa pe ojuṣe gbogbo wọn ni lati ri i pe ko si idọti kankan ni Kwara, ki wọn si ri i pe gbogbo ẹ n mọ tonitoni.

Ninu atẹjade kan ti Kọmisanna lẹka eto ilera Arábìnrin Banigbe Remilekun fi sita, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti ṣe alaye lori idi pataki to fi yẹ ki gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara maa samojuto  agbegbe wọn ko mọ tonitoni.

Arabinrin Banigbe ba ajọ gbaluu-mọ nipinlẹ Kwara sọrọ (Kwara State Environmental Production Agency) to si ni ki wọn maa fọwọ wẹwọ pẹlu ajọ to ku nipinlẹ naa lati lati ri i daju pe gbogbo opopo ipinlẹ Kwara mọ roro.

 

 

 

Leave a Reply