Oṣu meji sẹyin ni ọmọ ikoko ti iya rẹ gbe dani yii waye, ṣugbọn niṣe lo gbo naa to kuro lohun teeyan le dakẹ si. Ẹsẹkẹsẹ lo di ohun ti awọn eeyan n sọrọ ẹ lori ayelujara, nitori oju iya arugbo lọmọdebinrin naa gbe waye, irun ori rẹ ko si jọ tọmọ tuntun.
Orilẹ-ede South Africa ni wọn ti bi ọmọ yii, iya rẹ ko ju ẹni ọdun mejilelogun lọ.
Ki i kuku ṣe pe apẹẹrẹ buruku kan wa nigba ti iya rẹ loyun gẹgẹ bo ṣe wi, lọjọ to fẹẹ bi i paapaa, ko si wahala kan ju pe wọn ko tete ri mọto ti yoo gbe iya naa lọ sọsibitu, n lo ba bimọ sile.
Ọmọ naa delẹ tan lo di pe oju rẹ ko tiẹ wu eeyan, bẹẹ ni iya-iya rẹ sọ pe ko ke rara gẹgẹ bo ṣe yẹ kọmọ tuntun ke. Koda, ọmọ yii ko fi imu rẹ mi bi iya naa ṣe wi, o ni nibi iha ni mimi rẹ ti n jade, to si n han, eyi si mu ipaya ba awọn.
Apa ibi kan ti wọn n pe ni Libode Eastern Cape ni wọn ti bimọ yii ni South Africa, igba ti wọn si woju rẹ lẹyin ibimọ naa ti ko yipada, to jẹ niṣe lara rẹ hunjọ bii ara arugbo, ti gbogbo ọmọ ika ọwọ rẹ kako, ti ko na, ni wọn gbe e lọ sọsibitu lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an.
Nileewosan ni wọn ti jẹ ko ye wọn pe aisan buruku kan ti wọn n pe ni Progeria lo n ṣe ọmọ yii. Wọn ni aisan naa maa n jẹ keeyan gbo kọja ojọ ori ẹ, eeyan yoo si maa sare dagba ju ti ẹgbẹ rẹ lọ ni.
Dokita Martha Mayer, onimọ nipa itọju ọmọde nileewosan Nelson Mandela Academic Hospitals, ṣalaye pe ohun to n ṣe ọmọ ikoko yii ko wọpọ, ko si ki i saaba waye. O ni ninu miliọnu mẹrin eeyan, o le jẹ ẹni kan ṣoṣo ni iru ẹ maa ṣẹlẹ si, ṣugbọn ko sẹni to mọ ẹni kan oun, ẹnikẹni lo le jẹ.
Dokita Martha sọ pe ki i ṣe ẹjọ iya ti ọmọ rẹ ni aisan yii, bẹẹ ni ki i ṣe ẹjọ ọmọ to ṣẹlẹ si pẹlu, Ọlọrun nikan lo ye bo ṣe ri.
O ni awọn ọmọ ti kinni yii ba n ṣe ki i pẹẹ ku, nitori wọn ki i ni ẹmi gigun, aisan ọkan maa n da wọn laamu, ohun to n ṣe wọn yii si maa n bu ọjọ ori wọn ju bi wọn ṣe jẹ lọ, ko si le pẹ ti yoo fi ti wọn si koto.
Ko ti i si itọju kankan fun aisan yii gẹgẹ bi Dokita ṣe wi, boya lọjọ iwaju ṣa, boya o le ṣee ṣe.