Stephen Ajagbe, Ilorin
Awọn araadugbo Adeta, niluu Ilọrin, ti fa afurasi ẹni ọdun marundinlọgbọn kan, Isiaka, tọwọ tẹ nibi to ti lọọ ji pọmbu lara kanga-dẹrọ le awọn agbofinro lọwọ.
Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan oru lọwọ tẹ ọkunrin naa lasiko to n tu pọmbu ọhun.
Bi wọn ṣe mu u ni wọn ja sihooho, ti wọn si de e lapa ati ẹsẹ, ti wọn waa fa a le ileeṣẹ NSCDC lọwọ.
Ọmọkunrin naa ni adugbo Ita-Kudimoh, loun n gbe oun si niyawo atawọn ọmọ nile.
Awọn araadugbo ni ki i ṣe igba akọkọ ree tawọn ole yoo gbiyanju lati ji pọmbu naa gbe, idi niyi tawọn fi yan awọn eeyan ti yoo maa ṣọ ọ, ko too di pe ọwọ tẹ ọmọkunrin naa.
Molero pe ijoba yio dalejo gege bi ise owo re
Ero temi ni pe ki ijoba se dajo ti o ba ya Logan ki won ma fi fale