Oju ọmọ ọdun meji yii ri to, oṣu mẹrin lo ti bẹrẹ nnkan oṣu

Wọn ni bi arugbo ba ṣalaye ohun toju ẹ ri to fi ko sinu, ọmọde ko ni i fẹẹ dagba koju tiẹ naa ma baa riru ẹ. Ṣugbọn ewo ni ti ọmọde ti ko ti i dagba rara to ti n ti kekere ko si wahala isun ẹjẹ ati jẹjẹrẹ?

Njẹ ẹyin naa ti gbọ nipa ọmọdebinrin yii, Bibian, ti wọn bi lorilẹ-ede Kenya lọdun 2019, ṣugbọn to jẹ ọmọ oṣu mẹrin lo wa to ti bẹrẹ si i ṣe nnkan oṣu?

Faustine Andeso lorukọ obinrin to bi Bibian, iya naa ṣalaye fun ẹka iroyin The Standard, nile wọn to wa ni Likuyani, ni Kakamega County, Kenya. O ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2019, loun bi ọmọ oun yii, o si tobi pupọ, o wọn kilo mẹrin ati meji (4.2kg).

Ohun gbogbo n lọ nirọrun lẹyin ibi rẹ gẹgẹ bi iya ọmọ naa ṣe wi, afi nigba to pe oṣu mẹrin to si bẹrẹ si i gbe apẹẹrẹ ọlọmọge yọ.

Faustine sọ pe ọyan ọmọ oun bẹrẹ si i tobi, irun bẹrẹ si i yọ labiya ati oju ara ọmọ oṣu mẹrin naa, bẹẹ ni irore n ṣu si i loju. Ko pẹ lẹyin ti awọn ami yii jade lara rẹ lẹjẹ naa bẹrẹ si i jade loju ara rẹ bii igba tobinrin n ṣe nnkan oṣu.

Ohun to tiẹ waa mu ibẹru wa ni pe ọjọ marun-un bii tawọn obinrin agbalagba to n ṣe nnkan oṣu lẹjẹ Bibian naa fi n wa, ohun to jẹ ki iya rẹ sare gbe e lọ sileewosan niyẹn.

Iya naa tẹsiwaju pe awọn dokita fun ọmọ oun lawọn oogun apakokoro ti wọn n pe ni antibaotiiki (antibiotics), wọn tọju rẹ pe boya kokoro aifojuri kan ti wọ ọ lara ni, ṣugbọn iwosan naa ko mu nnkan kan wa, niṣe lẹjẹ tun wa loṣu to tẹle e, bo si ṣe di nnkan oṣooṣu niyẹn.

Iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ sọmọ naa lo mu baba rẹ sa lọ, o kọ Faustine atọmọ to n ṣe nnkan oṣu naa silẹ patapata, iya rẹ nikan lo si ku to n gbe e kiri ileewosan fun itọju.

O to asiko kan ti ọmọ naa ko le jẹun daadaa mọ, bẹẹ ni ko le mi daadaa pẹlu, nigba naa ni iya rẹ tun gbe e lọ sọsibitu kan ti wọn ti ni ko ṣe ayẹwo (scan) lati mọ ohun to n ṣe ọmọde naa gan-an.

Awọn dokita to ṣayẹwo fun Bibian loṣu kin-in-ni, ọdun to kọja yii, ṣalaye fun iya ẹ pe kinni kan wa labala ibi ti ọmọ naa yoo ti ṣabiyamọ, wọn ni kinni ọhun lo n dagba to fi di pe ọmọ kekere n ṣe bii agbalagba yii, afi ki wọn ṣiṣẹ abẹ ti wọn yoo fi mu un kuro.

Aṣe jẹjẹrẹ ile ọmọ lo n da a laamu, bẹẹ, ko ti i pe ọmọ ọdun kan rara nigba naa,’Sex cord stromal tumour’ ni wọn pe kinni naa. Lasiko ti wọn gbe e lọ fun iṣẹ abẹ yii, wọn ni jẹjẹrẹ naa ti wọ ipele keji (stage 2). Bẹẹ lawọn dokita bẹrẹ iṣẹ abẹ lara ọmọ to wa loṣu mẹjọ nigba naa, wọn yọ kinni ọhun kuro tan ni wọn tun bẹrẹ itọju ti wọn n pe ni chemotherapy, eyi si mu inira dani pupọ gẹgẹ bawọn dokita ṣe wi, iya rẹ paapaa loun kaaanu ọmọ to ti kekere ko sinu irora bii eyi, ṣugbọn ko sohun toun le ṣe si i.

Ni bayii, Bibian ti pe ọmọ ọdun meji ati oṣu marun-un, awọn dokita ti sọ pe jẹjẹrẹ ko ṣe e mọ. Wọn ni ṣugbọn o nilo awọn oogun atẹjẹṣe atawọn amarajipepe (multivitamin and immune boosters).

Wọn lawọn eyi ni yoo fi maa gbera lati koju aisan to ba fẹẹ kọ lu u, nitori itọju ti wọn n pe ni Chemotherapy yẹn ti sọ ọpọlọpọ eroja to n gbogun ti aisan lara rẹ di ọlẹ.

Iya rẹ naa royin ilẹ kun, o ni ohun to ṣẹlẹ sọmọ oun yii jẹ koun padanu iṣẹ, owo rẹpẹtẹ, awọn ọrẹ, ifọkanbalẹ ati igbeyawo oun. Faustina ni ṣugbọn gbogbo eyi ko to alaafia ọmọ oun to pada, nitori ohun to pa agbalagba mi-in ko to ida kan eyi ti ọmọ oun kekere la ja yii, o ni nnkan buruku aye gbaa ni jẹjẹrẹ.

Leave a Reply