Faith Adebọla, Eko
Bawọn ọlọkada to n tẹ ofin irinna ilu Eko loju ba lawọn o ni i gbọ, awọn agbofinro to n mu wọn naa ti lawọn ko ni i gba, wọn ni ṣinkun lawọn yoo maa fọwọ ofin mu wọn, tawọn yoo si maa gbẹsẹ le ọkada ati irinnṣẹ wọn, yatọ si pe awọn ọlọkada bẹẹ maa foju bale-ẹjọ.
Igbimọ amuṣẹya tijọba gbe kalẹ lati maa ri iwa irufin awọn ọlọkada naa sọ pe laarin ọsẹ kan pere, ọkada okoolenirinwo (420) ni awọn gba nidii awọn to gun un tabi awọn to ni wọn, tawọn si gbẹsẹ le wọn, latari bawọn ọkada naa ṣe n rin awọn ọna tijọba ti ka leewọ fawọn ọlọkada.
Ọga agba Lagos State Environmental and Special Offences Unit (Taskforce), CSP Ṣhọla Jẹjẹloye, sọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe lọjọ kan ṣoṣo pere, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an yii, ọkada aadọfa lawọn mu, tawọn si gbẹsẹ le fun rirufin irinna tijọba ṣe, bẹẹ awọn ti mu eyi to ju ọọdunrun ọkada lọ lọjọ marun-un sẹyin.
Jẹjẹloye ni eyi to pọ ju lọ ninu awọn ọkada naa lọwọ ba ni agbegbe Isọlọ, Ojodu si Berger, Ọjọta, Erekuṣu Eko, Surulere, Festac, Rainbow keji, ati titi marosẹ Sango si Oṣodi. O lo jẹ nnkan iyalẹnu pe bawọn ṣe n fi pampẹ ofin gbe awọn ọlọkada naa to, bẹẹ ni awọn arufin naa n kọti ikun si aṣẹ ijọba si i, ṣugbọn awọn o ni i kaaarẹ lati maa mu wọn.
Ọga agba naa parọwa sawọn araalu lati jawọ ninu gigun awọn ọkada loju ọna tijọba ti ka leewọ fun wọn, o ni akoba ni ọpọ ero toju n kan maa n ṣe fawọn ọlọkada naa, awọn ni wọn si tubọ n ki wọn laya lati maa tasẹ agẹrẹ sofin ijọba.
O ni anfaani araalu ni ofin tijọba ṣe wa fun, awọn o si ni i sinmi lati mu aṣẹ ijọba ṣẹ.