Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ni ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ogun nawọ gan ọkunrin yii, Hussaini Abdulsalam; ẹni ọdun mẹrinlelogun. Idi ni pe ọkada tawọn kan ji gbe n’Ijẹbu-Ode loun n gun kiri ni Ṣagamu.
Ohun to ṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi CP David Akinrẹmi ti i ṣe olori Amọtẹkun Ogun ṣe sọ ni pe awọn ọkunrin meji kan ni wọn pe ẹni to n gun ọkada naa n’Ijẹbu-Ode, pe ko gbe awọn lọ si otẹẹli kan niluu naa.
Nibi ti wọn ti n lọ ni wọn ti n ba ọlọkada ọhun ṣawada, to bẹẹ to jẹ wọn mu un lọrẹẹ, wọn si fun un ni nnkan mimu kan pe ko mu un.
Ọlọkada ko mọ pe wọn ti foogun sinu ohun ti wọn fun oun mu naa, bo ti mu un tan lo bẹrẹ si i toogbe, bẹẹ lawọn ọkunrin meji naa si ṣe gbe ọkada rẹ lọ raurau.
Wọn paarọ nọmba alupupu naa kuro ni “ Ogun TTD 439 VN, wọn sọ ọ di Ogun AAB 252 WI. Eyi ni Usman n gun kiri ni tiẹ ni Ṣagamu.
Iwadii ijinlẹ lawọn Amọtẹkun fi tọpinpin alupupu naa de ọdọ rẹ, nigba ti olobo ta wọn pe Hussaini ni ọkada ọhun wa lọdọ rẹ, n ni wọn ba mu un.
Nigba tawọn ẹṣọ yii fọrọ wa a lẹnu wo, Hussaini sọ fun wọn pe oun n tun alupupu naa ṣe ni, ati pe ẹnikan lo gbe e wa sọdọ oun pe koun ba oun tun un ṣe.
Wọn beere oruko ẹni to gbe ọkada fun un, ko ri nnkan kan wi, bẹẹ ni ko le sọ pato pe ibi bayii lẹni ọhun wa.
Bi wọn ṣe fa a le awọn ọlọpaa lọwọ niyẹn, l’Eleweeran, l’Abẹokuta.