Jọkẹ Amọri
Ọkan pataki ninu awọn oṣere ilẹ wa, Johun Adewuni ti gbogbo eeyan mọ si Tafa Oloyede ti ku o. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọkunrin naa ku lẹni ọdun mọkandinlaaadọrin nile rẹ to wa ni Arowomọle, laduugbo Kajọla, niluu Oṣogbo lẹyin aisan ranpẹ.
Ọmọ bibi ilu Ẹdẹ ni oṣere to jẹ ọmọ ẹyin Oloogbe Oyin Adejọbi yii.
Ko ti i sẹni to le sọ ohun to fa iku rẹ, ṣugbọn o to ọjọ mẹta ti wọn ti gburoo ọkunrin naa nidii ere tiata to yan laayo.
Lara awọn ere to ti kopa ni ‘Akanji Oniposi’, ‘Ekurọ Ọlọja’, ‘Jaiyesinmi’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iyawo atọmọ ni ọkunrin naa fi saye.