Faith Adebọla
Ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ apaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, (BOT) Joy Emordi, ti kọwe fipo rẹ silẹ, o si ti darapọ mọ ẹgbẹ APC.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni meje ninu awọn igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa (NWC), kọwe fipo silẹ, ti wọn ni awọn ko ṣe mọ, ko too waa tun di pe ọmọ ẹgbẹ wọn toun naa wa ni igbimọ apaṣẹ tun kọwe fipo silẹ, to si darapọ mọ ẹgbẹ APC.
Alaga fidi-hẹ ẹgbẹ APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Borno, Bala Buni lo gba obinrin naa sinu ẹgbẹ ọhun ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii niluu Abuja.
Oludari agba fun alaga fidi-hẹ yii, Malam Mamman Muhammed, to fidi ẹ mulẹ sọ pe obinrin naa loun gbagbọ pe ninu ẹgbẹ oṣelu APC nikan ni iṣọkan ati idagbasoke ti le ba ilẹ wa. Aridaju yii lo ni o mu ki oun pada sinu ẹgbẹ naa.
Emordi ni ẹgbẹ APC nikan lo n ja fun iṣọkan ati iduroṣinṣin Naijiria. Obinrin na ni inu oun dun pe ijọba n ṣiṣẹ, wọn si n ṣatilẹyin fun awọn eeyan apa ilẹ Guusu eyi to n mu ki ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ alatako maa darapọ mọ ẹgbẹ naa.
Tẹ o ba gbagbe, meje ninu awọn ọmọ igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa kọwe fipo wọn silẹ ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Alaga ẹgbẹ naa, Uche Secondus, ni wọn fẹsun kan pe ko jẹ ki awọn mọ nipa gbogbo ohun to n lọ ninu ẹgbẹ naa. Wọn ni oun nikan lo n da a ṣe, awọn ko si le ba iru eeyan bẹẹ ṣiṣẹ papọ mọ.