Ọkẹ aimọye dukia ṣofo ninu ijamba ina to ṣẹlẹ l’ọja Ipata, ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Loru mọju ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni ina nla ṣọṣẹ ni ọja kan to gbaju-gbaja ti wọn ti n ta ẹran ati nnkan miiran, ti wọn n pe ni ọja Ipata, to wa ni agbegbe Ipata, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti dukia olowo iyebiye si jona gburugburu.

Baba lọja ọja naa to fidi ìṣẹ̀lẹ̀ naa mulẹ, Dauda Alabi, sọ pe awọn kan ni wọn n sun akiitan ni alẹ Ọjọruu, ṣugbọn nigba to di oru, ni afẹfẹ gbe ina ọhun, to si ran mọ awọn maaluu ati awọn ẹran ti wọn so mọlẹ, ko too di pe ina ọhun tun bẹrẹ si ni i jo awọn ṣọọbu.

Ọpọ dukia ni wọn padanu sọwọ ina nibi iṣẹlẹ agbọ-bomi loju naa. Ogunlọgọ ewurẹ, aguntan, maaluu ati owo iyebiye lo ba iṣẹlẹ naa lọ. Dauda ṣalaye siwaju pe awọn ọlọja kan ti wọn rinrin-ajo lati lọọ ra ọja ti wọn ko ri ra ni wọn gbowo sinu ṣọọbu pe awọn yoo mu irin-ajo awọn pọn lọjọ keji, ni gbogbo owo wọn jona mọ inu ọja naa bayii, bo ti lẹ jẹ pe wọn ko darukọ iye to jona.

Leave a Reply