Monisọla Saka
Akọwe awọn igbimọ to n ṣeto ipolongo ibo atawọn eto mi-in ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Eko, Ayọdele Adewale, ti jade sita bayii lati wẹ ọga ẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, mọ pe awọn ọkọ ti wọn fi n gbe owo rin, Bullion van, ti wọn ri ninu ọgba ile ẹ lọjọ ti ibo aarẹ ọdun 2019 ku ọla ṣina wọle rẹ ni, ki i ṣe oun lo ko wọn sibẹ.
Lasiko to n ṣe ifọrọwerọ lori Arise TV, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lo sọrọ naa. Adewale ni, ọrọ to ti ku, to ti jẹra, lawọn eeyan tun lọọ gbe dide pada, nitori ọrọ ti wọn ti fi ti sibi kan latọjọ to ti pẹ lọrọ ọkọ agboworin ọhun.
O ni, “Lori ọrọ ọkọ agboworin abi ki i ṣe ọkọ agboworin ti wọn n sọ yii, mo lero pe ọrọ yẹn ti lọ sodo lọọ mumi ni. Ko sowo kankan ninu awọn ọkọ yẹn. Ṣe awọn ọkọ to tiẹ tun jẹ pe wọn ṣina wọle Aṣiwaju ni.
Lọjọ naa lọhun-un, inu ile yẹn ni mo wa, ki i si i ṣe ọjọ idibo gan-an naa. O ni lati jẹ pe awọn ọkọ agboworin yẹn sọnu ni wọn fi ṣi ile Aṣiwaju ya”.
Nigba to n sọrọ siwaju si i lati le fidi ohun to n sọ mulẹ, o ni, “Awọn ileeṣẹ kan wa ti wọn lawọn ogunlọgọ oṣiṣẹ, to jẹ pe owo kiṣi bayii ni wọn fi n sanwo oṣu awọn oṣiṣẹ wọn dipo ki wọn san an sinu banki fun wọn. Dajudaju, awọn ọkọ yẹn ṣina ni, ki i ṣe Aṣiwaju tabi ẹnikẹni lo ranṣẹ pe wọn”.
Ọrọ ti Adewale sọ yii yatọ gedegede sohun ti Tinubu sọ lori ọrọ awọn ọkọ yii lọdun 2019. Alaye to ṣe lori awọn ọkọ agboworin mejeeji ti wọn wọnu ile ẹ to wa ni Bourdillon, Ikoyi, nipinlẹ Eko, lasiko ti wọn n bi i lawọn ibeere ni pe, ibi to ba wu olowo lo le tọju owo ẹ si, bo ba ṣe wu oun, ibikibi to ba si wu oun, loun le kowo oun si.
Ni kete to dibo tan lọdun 2019, tawọn oniroyin n takoto ibeere si i ni Tinubu da wọn lohun pe, “Ẹ jọọ naa, ṣe owo mi lẹ n sọ yii abi owo ijọba? O yẹ kẹ ẹ mọ pe mi o ṣiṣẹ fun ijọba tabi labẹ ijọba kankan. Mi o si labẹ ileeṣẹ ijọba kankan, ẹni to ba si ro pe irọ ni, ki iru ẹni bẹẹ jade sita lati waa ta mi laya pe ijọba Buhari gbe iṣẹ akanṣe kan fun mi, abi boya ijọba APC, lati bii ọdun marun-un sẹyin ti wọn ti wa nibẹ lo si gbe iṣẹ kan fun lati le jere nibẹ ni. Ki wọn jade wa pẹlu ẹri lati fidi ododo mulẹ.
“Emi da duro ni o, ẹgbẹ oṣelu mi ni mo si n ba ṣe tọkantọkan. Ti n ba waa lowo ti mo fẹẹ na ninu ile tabi ayika ile mi, ewo ni tiyin nibẹ? Ti mi o ba ṣoju ileeṣẹ ijọba Kankan, ti mo si lowo ti mo le na, bo wu mi, ma a fawọn eeyan lọfẹẹ lofo, niwọnba igba ti mi o ba ti fi ra ibo.
Ṣaa, ko sẹni to mọ ẹni to n sọ ootọ ọrọ laarin Tinubu to nile ti ọkọ gbe owo wọ, ati Adewale to loun kan lọọ ṣabẹwo lasan si Aṣiwaju lọjọ naa ni, to si ni ko sowo ninu ọkọ naa. Bẹẹ lẹnikan ko le sọ boya funra awọn ọkọ ni wọn ṣi ilẹkun wọle tabi awọn ẹṣọ alaabo ni wọn ṣilẹkun nla fun wọn lati wa mọto wọle.