Stephen Ajagbe, Ilorin
Afurasi ọgbọn to n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara tawọn eeyan mọ si ‘yahoo-yahoo’, lọwọ ajọ to n gbogun tiwa jibiti, EFCC, nipinlẹ Kwara, tẹ niluu Ilọrin, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pẹlu oriṣiriiṣi oogun.
Awọn afurasi naa ni; Adigun Ọladapọ, Ọlamilekan Ogunṣọla, Fuad Abidemi, Haastrup Samuel, Ọlamide Adeyẹmi, Akinọla Abideen, Ebenezer Haastrup, Kẹhinde Adeyẹmi, Quadri Kareem, Abubakar Abdulbashit, Damilọla Akinọla, Ọla-Oluwa Samuel, David Oyewọle, Mojereọla Tọheeb, Isaac Chikezie, Joshua Chiekezie, Abdulsalam Ọpẹyẹmi ati Abawọnjo Abdulazeez.
Awọn to ku tun ni; Ganiyu Ọlanrewaju, Adeleke Ibrahim, Taiwo Ganiyu, Ọkẹ Gideon, Ọlakunle Adebisi, Ajani Samuel, Joshua Ogizien, Sọdiq Ọlaṣupọ, Ọlamilekan Mubarak, Adeniyi Ọlaṣhile, Rotimi Adeyẹmi ati Rasaq Ọlanrewaju.
Ajọ EFCC ni ọpọlọpọ ninu awọn afurasi naa jẹ akẹkọọ, kaakiri igboro ilu Ilọrin lawọn ti ri wọn ko, lẹyin tawọn eeyan kan ta awọn lolobo.
Ọkọ ayọkẹlẹ olowo nla mẹwaa ọtọọtọ, oriṣiriiṣii foonu, kọmputa alagbeeka atawọn nnkan mi-in ni wọn tun ri gba lọwọ wọn.
EFCC ni lẹyin iwadii, awọn yoo wọ wọn lọ sile-ẹjọ.