Ẹ sọ funjọba ko tete san ọgọrun-un miliọnu fawọn ajinigbe ko too pẹ ju – Sheik Gumi

Faith Adebọla

 Aṣaaju ẹsin Islam nilẹ Oke-Ọya nni, Sheik Ahmad Gumi, ti sọ pe kawọn ti wọn ba mọ ibi ti eti ijọba wa, ati ibi ti ọrọ ti le wọ eti ọhun tete yaa fa ijọba leti mọra pe ki wọn ma fọwọ yọbọkẹ mu ọrọ gbedeke tawọn janduku agbebọn sọ nipa awọn akẹkọọ to wa nigbekun wọn, o ni kijọba ṣeto lati san miliọnu ọgọrun-un (N100m) ti wọn beere fun.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lọkunrin naa sọrọ ọhun nigba to n dahun awọn ibeere kan tileeṣẹ iweeroyin Punch fi sọwọ si i lori iṣẹlẹ naa, o ni imọran oun ni pe kijọba apapọ paṣẹ fun banki apapọ ilẹ wa lati sanwo tawọn ajinigbe naa beere fun wọn.

Ṣe, lọjọ Aje, Mọnde yii, ni ọkan ninu awọn ajinigbe agbebọn ọhun ti wọn porukọ ẹ ni Sani Jalingo ti sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lede Hausa pe miliọnu ọgọrun-un ati ọkada tuntun mẹwaa lawọn maa gba ki wọn too le da awọn akẹkọọ Fasiti Greenfield ti wọn ji gbe lọsẹ to lọ lọhun-un niluu Kaduna, silẹ lominira.

Sani ni ki i ṣe pe wọn gbọdọ san owo ati ọkada nikan, wọn o tun gbọdọ kọja ọjọ Tusidee (ọjọ kẹrin, oṣu karun-un yii) ki wọn too ṣe e, aijẹ bẹẹ, niṣe lawọn maa fi ẹmi awọn akẹkọọ naa ṣofo danu ni. O lawọn maa fibinu pa wọn danu ni.

Bakan naa lo sọ pe miliọnu marundinlọgọta tawọn ti gba lọwọ awọn obi awọn ọmọ naa, ounjẹ tawọn fi bọ awọn akẹkọọ naa lo ba lọ, tori ẹ lawọn ṣe n beere owo mi-in lakọtun.

Sheik Gumi ni “Owo ti wọn n beere yii, wọn o le ko o sa lọ. Ko ṣẹni to le sa lọ ninu wọn. Ki lo waa de tijọba o kọkọ san owo ti wọn n beere fun na, ki wọn le ri awọn akẹkọọ ọhun gba pada, ti wọn ba si ti tu awọn akẹkọọ naa silẹ tan, kijọba waa lepa wọn, ki wọn si gba owo ti wọn gba naa lọwọ wọn?

“Tijọba ba fọrọ gbigba awọn akẹkọọ yii falẹ ju, awọn janduku naa le lọọ da ẹmi wọn legbodo, wọn si le tawọn fawọn eeṣin-o-kọku Boko Haram ti wọn lowo lọwọ ju ijọba lọ, ti wọn si tun ni nnkan ija gidi. Tori ẹ, kijọba wa nnkan ṣe kia kiyẹn too ṣẹlẹ ni.” Bẹẹ ni Gumi sọ.

Leave a Reply