Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Eeyan meji padanu ẹmi wọn, ọpọ fara pa, ninu ijamba ọkọ ọlọpaa ati kẹkẹ to ṣẹlẹ lowurọ kutukutu ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, nikorita Sango, lagbegbe Agric, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Ni awọn onikẹkẹ ati ọlọpaa ba fija pẹ ẹ ta.
ALAROYE gbọ pe ọkọ ọlọpaa kan Toyota Hiliux, lo n sare asapajude, to si gun ori kẹkẹ Maruwa mẹta lẹẹkan ṣoṣo, eeyan meji ku loju-ẹṣẹ, awọn miiran si fara pa yanna yanna. Eyi lo fa a ti gbogbo Opopona Sango ṣe di pa, awọn to n lọ ko ribi lọ, awọn to n bọ naa ko ri ọna gba, ṣe ni gbogbo eeyan kawọ lori, ti wọn kigbe ikunlẹ abiyamọ o.
Inu bi awọn onikẹkẹ Maruwa yooku, wọn lọọ ba dẹrẹba to wakọ ọlọpaa, wọn ṣa a ladaa, ṣugbọn ko wọle, ni dẹrẹba naa ba sa lọ. Awọn onikẹkẹ ba mọto ọlọpaa naa jẹ, wọn tun fẹẹ dana sun ọkọ naa, lawọn ọlọpaa ba binu tan.
Awọn ọlọpaa rọ debi iṣẹlẹ naa, wọn kọkọ bẹrẹ si i yin afẹfẹ tajutaju, sugbọn nigba to ya, wọn bẹrẹ si i yinbọn soke, awọn onikẹkẹ naa bẹrẹ si i sa asala fun ẹmi wọn. Awọn ọlọpaa ba n ko gbogbo kẹkẹ Maruwa ti wọn ri, ti wọn si tun mu gbogbo onikẹkẹ ti wọn ri.