Ọkọ tẹ awọn ọmọ ‘Yahoo’ meji pa n’Idanre, lawọn ẹgbẹ wọn ba fẹhonu han

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku kọrọ iku awọn ọmọ ‘Yahoo’ meji ti wọn ku sinu ijamba ọkọ lagbegbe Idanre, nijọba ibilẹ Idanre, da rogbodiyan nla silẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ilu Idanre lawọn ọmọ ‘Yahoo’ ọhun ti gbera pẹlu ọlọkada kan to gbe wọn lọjọ naa, ti wọn si mori le ọna igboro Akurẹ pẹlu ere asapajude ti ọkunrin ọlọkada yii n sa.

Bo ṣe ku bii ibusọ meji pere ki wọn wọ igboro ilu Akurẹ lo ba ọkọ kan niwaju, ibi to ti n gbiyanju ati ya ọkọ yii silẹ lori are, ọkọ akoyọyọ to n ba ere bọ niwaju lo lọọ fori sọ.

Loju-ẹsẹ lawọn ọmọ ‘Yahoo’ meji to jokoo lẹyin ọkada náà ti ku, ti ọkùnrin ọlọkada tó gbé wọn si wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun títí di ba a ṣe n kọ iroyin yii lọwọ.

Ko ju bii ọgbọn iṣẹju tiṣẹlẹ yii waye nigba ti ọgọọrọ awọn ọmọ ‘Yahoo’ kan lati ilu Idanre ya de lati fẹhonu han ta ko iku awọn ẹgbẹ wọn mejeeji.

Ọkọ akoyọyọ to tẹ wọn pa ni wọn kọkọ sọ ina si ki wọn too bẹrẹ si i daamu awọn ọlọkọ atawọn eeyan to rìn si asiko ti iṣẹlẹ yii waye.

 

Leave a Reply