Faith Adebọla, Eko
Korona, arun aṣekupani to ti di ẹrujẹjẹ kari-aye nni, ṣi n ṣoro bii agbọn, paapaa nipinlẹ Eko, pẹlu bijọba ṣe kede pe eeyan bii okoolerugba lo ṣẹṣẹ lugbadi arun naa lọjọ Aiku, Sannde yii, tawọn mẹta mi-in ko si ribi yẹ ẹ si, kinni naa pa wọn lẹyẹ-o-sọka.
Ikede ti ajọ to n ri si ajakalẹ arun nilẹ wa, National Centre for Disease Control, (NCDC) kede laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, pe ọtalelọọọdunrun ati marun-un lawọn ti ayẹwo fihan pe Korona ti mu wọn lọjọ Sannde, kaakiri orileede yii, okoolerugba lara wọn jẹ nipinlẹ Eko, eeyan mẹta si larun ọhun lu pa nipinlẹ naa.
Lọjọ kan naa, eeyan mejila ti wọn ti n gba itọju tẹlẹ ni wọn da silẹ pe ki wọn maa lọọ ile wọn, ayẹwo fihan pe ara wọn ya, aisan ọhun ti fi wọn silẹ.
Ajọ naa ni lọjọ Satide to ṣaaju, eeyan meji lo ku iku Korona, nigba tawọn lo lugbadi rẹ jẹ igba ati mejila (212).
Titi dasiko yii, nipinlẹ Eko, aropọ awọn ti wọn ti lugbadi arun ọhun jẹ ẹgbẹrun marundinlọgọrun ati aadọrun-un (75,090), ara ẹgbẹrun lọna aadọrun ati ojilelẹgbẹta o le mẹwaa (70,650) lara wọn ti ya lẹyin itọju, ṣugbọn ọtalelẹgbẹta o din marun-un ni wọn ba ajakalẹ arun buruku yii rin, wọn doloogbe.
Ajọ NCDC ṣekilọ pe tiṣọratiṣọra ni kawọn eeyan maa rin lasiko yii, ki wọn ma ṣe tura silẹ lori gbigba eewọ arun naa, paapaa lilo ibomu ati fifọwọ wọn deede.