Ọkunrin ti wọn ka ẹya ara eeyan mọ lọwọ l’Ọṣun ni akoba ni

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Bo tilẹ jẹ pe ariwo ‘wọn ko ba mi’ ni ọkunrin kan n pa lasiko ti awọn eeyan ilu Igẹgẹ, nipinlẹ Ọṣun, ka oriṣiiriṣii ẹya ara eeyan mọ ọn lọwọ, sibẹ, alubami ni wọn na an ko too di pe awọn ikọ Amọtẹkun gba a silẹ.

A gbọ pe lasiko ti ọkunrin naa n lọ kaakiri pẹlu baagi ‘Ghana must go’ kan lọwọ rẹ lawọn araalu da a duro, ti wọn si beere pe ki lo di sinu baagi.

Nigba ti ọkunrin yii ko tete ri esi fọ fun wọn ni wọn bẹrẹ si i na an, ti wọn si ni ko ṣi baagi naa, ko si tu nnkan to wa ninu rẹ jade.

Bo ṣe ṣi baagi ti wọn ba oriṣiiriṣii ẹya ara eeyan ninu ẹ lariwo sọ, ṣugbọn ṣe lọkunrin yii n tẹwọ pẹbẹ pe oun ko mọ nnkan kan nipa nnkan ti wọn ba ninu baagi naa ati pe akoba lasan ni.

A gbọ pe ọrọ iba yiwọ fun ọkunrin naa bi ki i baa ṣe ti awọn Amọtẹkun ati awọn ọlọpaa ti wọn tete debẹ lati gbe e.

Alaga ijọba ibilẹ agbegbe Ila-Oorun Guusu ỌlaOluwa, Sunday Ọlaifa, ṣalaye pe iṣẹlẹ naa nilo ki awọn agbofinro ṣiṣẹ iwadii to kunna le e lori.

O ni nigba ti oun debẹ, ohun ti ọkunrin naa n tẹnu mọ ni pe akoba niṣẹlẹ naa, ni nitori latigba ti oun ti lọọ mu ọmọ tiyawo oun bi sile ọkọ akọkọ kuro lọdọ ọkunrin kan to n fojoojumọ jẹ ẹ niya lọkunrin naa ti sọ pe afi ki oun sun oun dẹwọn.

Ọlaifa fi kun ọrọ rẹ pe ọkunrin ti afurasi yii n tẹnu mọ pe o ko ba oun naa lo lọọ ke si awọn araalu lati fura si baagi to n gbe kaakiri ilu, to si tun lọọ fi to awọn ọlọpaa leti.

 

Leave a Reply